Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 8, 2020
BỌ̀GÉRÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre ní Bọ̀géríà

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre ní Bọ̀géríà

Ní November 10, 2020, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ECHR) dájọ́ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà ti fi ẹ̀tọ́ àwọn ará wa dù wọ́n láti ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n fẹ́. Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti parí iṣẹ́ ìkọ́lé Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ìlú Varna, lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Ó lé lọ́dún mẹ́wàá tí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé yìí ti wà nílé ẹjọ́. Bákan náà, ilé ẹjọ́ ECHR pàṣẹ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà san ohun tó lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rin àbọ̀ náírà (₦4,684,800.00), ìyẹn ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá àbọ̀ owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($11,500), fún àwọn ará wa gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

Ẹjọ́ náà dá lórí iṣẹ́ ìkọ́lé Gbọ̀ngàn Ìjọba tí à ń kọ́ lórí ilẹ̀ kan táwọn ará wa rà ní January 2006. Ọ́fíìsì ìjọba nílùú Varna fọwọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ní May 2007, àwọn ará wa sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́ lóṣù July, aláṣẹ ìlú náà dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró, ó ní wọn ò kọ́ ilé náà bó ṣe yẹ. Ní oṣù yẹn kan náà, ẹgbẹ́ òṣèlú kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní Bọ̀géríà lẹ ìwé mọ́ ibi tá a ti ń kọ́lé náà, wọ́n sì kó èrò rẹpẹtẹ wá ṣe ìwọ́de níbẹ̀ pé àwọn ò fara mọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ níbẹ̀.

Bó ṣe wà nínú ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe, ọ́fíìsì ìjọba nílùú Varna gbé ìkéde kan jáde tí wọ́n fi bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì sọ pé “àwọn tó ń ṣe ìwọ́de yẹn làwọn fara mọ́ láìkù síbì kan.” Aláṣẹ ìlú yẹn tún sọ fún àwọn oníròyìn pé òun fara mọ́ ìwọ́de náà.

Ó hàn kedere pé aláṣẹ ìlú náà àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ ń ṣe ẹ̀tanú sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n ní kì í ṣe pé àwọn kórìíra ẹ̀sìn kankan, pé ọ̀rọ̀ táwọn fẹ́ yanjú nípa òfin tó dá lórí irú ilé tó yẹ kí wọ́n kọ́ sí àdúgbò kọ̀ọ̀kan ló mú káwọn dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró.

Àwọn ará wa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sáwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Bọ̀géríà lóríṣiríṣi, títí kan Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní orílẹ̀-èdè náà, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ náà ò yanjú. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ìjọ tó wà ní àdúgbò yẹn ní láti lọ háyà ibì kan tí wọ́n á ti máa ṣe ìpàdé.

Ilé ẹjọ́ ECHR sọ pé ohun táwọn aláṣẹ yẹn ṣe kò bófin mu rárá. Adájọ́ mẹ́fà nínú méje ló fara mọ́ ẹjọ́ tí wọ́n dá náà pé, bí àwọn aláṣẹ ìlú Varna ṣe lọ dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró, wọ́n ti tàpá sí òfin tó dá lórí “ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní sí ìrònú, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn tó wù wọ́n” bó ṣe wà ní abala kẹsàn-án àti ìkọkànlá nínú Àdéhùn Àjọṣe ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.

Àwọn ará wa retí pé àwọn aláṣẹ ìlú náà máa ṣe ohun tí ilé ẹjọ́ ECHR sọ yìí. Wọ́n á sì gba àwọn láyè láti parí iṣẹ́ ìkọ́lé ibi ìjọsìn tó máa ṣe àwọn ará ìlú láǹfààní, tó sì máa fìyìn fún orúkọ Jèhófà ní ìlú Varna. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé kò fìgbà kankan fi wá sílẹ̀.—Sáàmù 54:4.