FEBRUARY 14, 2017
BỌ̀GÉRÍÀ
Ṣé Àwọn Ilé Ẹjọ́ ní Bọ̀géríà Máa Fọwọ́ sí I Pé Àwọn Aráàlú Lómìnira Ẹ̀sìn?
Ní June 4, 2016, Nikolai Stoyanov dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tó pàtẹ ìwé sí níta gbangba nílùú Burgas, kí àwọn tó ń kọjá lọ lè wá mú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́fẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá fẹ́. Nígbà tó di nǹkan bí aago méje ìrọ̀lẹ́, àwọn ọlọ́pàá dé. Wọ́n fẹ̀sùn kan Nikolai pé ó rú òfin ìlú, wọ́n sì bu owó ìtanràn lé e, wọ́n ní kó san dọ́là mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà márùn-ún tí wọ́n fẹ̀sùn kàn nílùú Burgas láàárín oṣù May àti June, tí wọ́n sì ní kí wọ́n sanwó ìtanràn torí pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn wọn, bẹ́ẹ̀, ìrọwọ́rọsẹ̀ ni wọ́n ń ṣe é.
Ilé Ẹjọ́ Sọ Pé Ofin Ìlú Kò Jẹ́ Kí Àwọn Aráàlú Lómìnira Ẹ̀sìn
Nikolai àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin tó kù pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n yìí àti owó ìtanràn tí wọ́n ní kí wọ́n san. Nígbà tó di October àti November 2016, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Burgas dá Nikolai àtàwọn Ẹlẹ́rìí yòókù láre, wọ́n sì fagi lé owó ìtanràn tí wọ́n bù lé wọn.
Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì fẹ́ kí ilé ẹjọ́ dá sí ohun tó ń lọ ní Burgas, bóyá òfin ìlú náà bá òfin ìjọba mu. Ní October 12, 2016, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìlú Burgas sọ pé òfin tí wọ́n ṣe nílùú náà láti fi ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò kí wọ́n má bàa ṣe ẹ̀sìn wọn ta ko òfin ìjọba orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà àtàwọn àdéhùn tí wọ́n fọwọ́ sí lábẹ́ ìjọba àpapọ̀ pé àwọn máa jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn.
Àjọ Ìlú Burgas ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Òfin Ìlú ta ko ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn aráàlú ní lábẹ́ òfin. Lọ́dún 2013, ṣe ni ẹgbẹ́ òṣèlú kan sọ pé kí àwọn aláṣẹ tún Òfin Ìlú ṣe, wọ́n ní àwọn kan nílùú ń ṣàròyé nípa iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Nígbà tí gómìnà tó wà lórí àlééfà nígbà yẹn gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ó sọ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀tanú ti wọ̀ ọ́, ó sì sọ pé àwọn àtúnṣe náà ò bófin mu. Àmọ́ nígbà tí gómìnà míì débẹ̀, ó fọwọ́ sí i, àjọ ìlú sì tún òfin náà ṣe. Àwùjọ àwọn alárinà aráàlú àti ìjọba kìlọ̀ fún àjọ ìlú pé òfin tuntun tí wọ́n gbé kalẹ̀ yìí ò bá òfin ìjọba mu, àmọ́ wọ́n kọ etí ikún. Òun ni wọ́n ń lò, kó tó wá di pé Ilé Ẹjọ́ Ìlú Burgas fagi lé e.
Irú ẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ nílùú Kyustendil. Àjọ ìlú yìí náà mọ̀ọ́mọ̀ tún òfin ìlú ṣe kí wọ́n lè fi ká àwọn aráàlú lọ́wọ́ kò, kí wọ́n má bàa lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Wọ́n wá sọ fún àwọn ọlọ́pàá ìlú pé kí wọ́n máa mú àwọn tí kò bá tẹ̀ lé òfin ọ̀hún. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà ni wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn pé wọ́n rú òfin yìí, wọ́n ní wọ́n ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu, wọ́n sì ní kí wọ́n san owó tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mọ́kàndínlógójì [439] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àmọ́ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìlú Kyustendil dá àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà láre, wọ́n sì fagi lé owó tí wọ́n bù lé wọn. Nínú ọ̀kan lára àwọn ẹjọ́ yìí, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin sọ pé: “Ẹni yìí lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ Òfin láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú, Òfin Ẹ̀sìn tí ìjọba ṣe sì fọwọ́ sí i. Wọ́n tún wá mú un lórí ẹ̀tọ́ rẹ̀.” Ní June 24, 2016, ilé ẹjọ́ yìí kan náà fọwọ́ sí ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú náà kọ sí wọn, wọ́n sì fagi lé òfin tí ìlú ṣe pé kò bá òfin ìjọba mu. * Àjọ Ìlú Kyustendil ti kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Ẹnu Àwọn Aláṣẹ Ò Kò Lórí Ọ̀rọ̀ Òmìnira Ẹ̀sìn
Láti ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ó kéré tán, ìlú mẹ́rìnlélógójì [44] ní Bọ̀géríà ni àwọn aláṣẹ ti tún òfin ìlú ṣe kí wọ́n lè ká àwọn ẹlẹ́sìn lọ́wọ́ kò kí wọ́n má bàa ṣe ẹ̀sìn wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Táwọn aláṣẹ bá sì ti ṣòfin yìí, ó máa ń ṣàkóbá fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé àwọn aláṣẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà sí wọn láti kìlọ̀ fún wọn, wọ́n á pè wọ́n lẹ́jọ́, wọ́n á bu owó ìtanràn lé wọn, wọ́n á máa halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n tiẹ̀ tún máa ń hùwà ipá sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, ní March 26, 2016, Marin Tsvetkov, tó jẹ́ ọlọ́pàá nílùú Vratsa halẹ̀ mọ́ àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ní òun máa pe àwọn jàǹdùkú oníbọ́ọ̀lù sí wọn, kí wọ́n kọ́ wọn lọ́gbọ́n. Ó wá gba àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn, ó sì ba àwọn kan lára rẹ̀ jẹ́.
Àmọ́ láwọn ibòmíì, àwọn aláṣẹ tí kì í ṣojúsàájú àtàwọn ilé ẹjọ́ kan ní Bọ̀géríà ti jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn. Bí àpẹẹrẹ, ní June 2, 2016, àwọn aláṣẹ mẹ́ta lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó pàtẹ ìwé sórí ohun tó ṣeé tì kiri nílùú Sofia tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Wọ́n bi wọ́n bóyá wọ́n gbàwé àṣẹ kí wọ́n tó máa ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda-ara-ẹni tí wọ́n ń ṣe yìí. Lẹ́yìn táwọn aláṣẹ náà ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n rí i pé Òfin orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú iṣẹ́ àlàáfíà yìí. Nílùú Plovdiv, tó jẹ́ ìlú kejì tó tóbi jù lórílẹ̀-èdè náà, ẹgbẹ́ òṣèlú kan ń gbìyànjú láti ṣàtúnṣe sí Òfin Ìlú àti Ààbò Aráàlú kí àwọn aláṣẹ lè fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ àjọ ìlú ò gbà kí wọ́n ṣe é.
Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ tí Ọ̀rọ̀ Àwọn Ìlú Tó Tún Òfin Wọn Ṣe Bá Dé Ilé Ẹjọ́?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Bọ̀géríà ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti pe ẹjọ́ lórí àwọn aláṣẹ ìlú mẹ́rìnlélógójì [44] tí wọ́n ṣòfin láti fi ẹ̀tọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ní láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ dù wọ́n. Krassimir Velev, tó jẹ́ agbẹjọ́rò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà, èyí tó wà nílùú Sofia, sọ pé: “Ìrànwọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe fún ìlú, torí ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ni wọ́n ń bá wọn sọ, wọ́n sì ń fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọn lọ́nà tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ gbọ́rọ̀ wa, àmọ́ láwọn ìlú tí àwọn aláṣẹ ti tún òfin ṣe, ṣe ni wọ́n dájú sọ wá torí pé à ń fún àwọn èèyàn níwèé lọ́fẹ̀ẹ́, tí a sì ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Láwọn ìgbà tá a bá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu ká gbèjà ẹ̀tọ́ tá a ní, a máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, torí ohun iyebíye ni òmìnira tá a ní láti jọ́sìn, Ọlọ́run ló sì fún wa ní ẹ̀tọ́ yìí.”
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé ọ̀pọ̀ àwọn lọ́gàálọ́gàá àtàwọn ilé ẹjọ́ ní Bọ̀géríà ló ń jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn, gbogbo ìlú lèyí sì ń ṣe láǹfààní. Ká ṣì máa wo ohun táwọn aláṣẹ máa ṣe sáwọn ìlú tí wọ́n ti tún òfin wọn ṣe kí wọ́n lè ṣèdíwọ́ fún òmìnira táwọn aráàlú ní láti ṣe ẹ̀sìn wọn ní Bọ̀géríà.
^ ìpínrọ̀ 7 Ìjọba orílẹ̀-èdè Bọ̀géríà tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn European Convention on Human Rights, èyí tó fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú, kó sì ṣe ohun tó gbà gbọ́, kó fi kọ́ni, kó máa tẹ̀ lé e, kó sì jọ́sìn. Léraléra ni Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù àti àjọ European Commission for Democracy Through Law (ìyẹn Àjọ ti Ìlú Venice) ti ń sọ ọ́ pé àdéhùn yìí gba àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti máa pàdé pọ̀ fún ìjọsìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀, kí wọ́n sì máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn aládùúgbò wọn.