Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 10, 2019
BRAZIL

Àkànṣe Ìwàásù Dé Àwọn Abúlé Lórílẹ̀-Èdè Brazil

Àkànṣe Ìwàásù Dé Àwọn Abúlé Lórílẹ̀-Èdè Brazil

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń sapá láti wàásù dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé ní àwọn abúlé tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil. Àkànṣe ìwàásù yìí bẹ̀rẹ̀ ní September 1, 2018, á sì máa báa lọ títí di December 31, 2019. Títí di báyìí, àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin (80,000) ló ti kópa nínú iṣẹ́ náà, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún (16,000) lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Orílẹ̀-èdè Brazil ni orílẹ̀-èdè karùn-ún tó tóbi jù lọ lágbàáyé. Àwọn tó sì ń gbé láwọn abúlé ibẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n (28,000,000). Àwọn mílíọ̀nù méjìlélógún (22,000,000) míì sì tún ń gbé láwọn àdádó. Àkànṣe ìwàásù yìí ti dé ìpínlẹ̀ ìwàásù tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600). Àwọn akéde kan tiẹ̀ rin ìrìn-àjò tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) kìlómítà (ìyẹn 1,243 máìlì) kí wọ́n lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn.

Akéde kan wàásù dé ilé kan, ó bá bàbá kan níbẹ̀ tó ń ṣa èso kọfí. Bàbá yẹn sọ fún un pé kó wọlé, ó wá nahùn pe ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ni wọ́n wá bá wa sọ. Jẹ́ ká gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ!”

Bàbá náà àti ìyàwó rẹ̀ béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè. Wọ́n béèrè nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú, kí nìdí tí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìjìyà? Ṣé ó yẹ kí èèyàn máa san ìdámẹ́wàá? Báwo lèèyàn ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro ìdílé? Wọ́n tún béèrè nípa oríṣiríṣi àwọn nǹkan míì. Bàbá yìí rí ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ẹ̀yìn ìgbà náà ló ṣàlàyé pé òun ti gbàdúrà láàárọ̀ ọjọ́ yẹn pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ kí òun lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Fún ìgbà àkọ́kọ́, bàbá yìí àti ìdílé rẹ̀ wá sí ìpàdé wá nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nìṣó.

Lágbègbè kan, àwọn ará ń wàásù láti ilé-dé-ilé nígbà tí òjò ńlá kan bẹ̀rẹ̀. Ní wọ́n bá sá sí ilé ìwòsàn ìjọba kan kí wọ́n lè forí pamọ́ fún òjò náà. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, wọ́n béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan àti ọmọ ẹ̀ pé ìbéèrè wo ló máa wù wọ́n kí wọ́n bi Ọlọ́run. Ọmọ yẹn sọ pé ó wu òun láti rí ìyá òun àgbà tó ti kú. Àwọn akéde náà ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde fún wọn, wọ́n sì tún fi fídíò Àjíǹde Máa Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́ hàn wọ́n.

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ará pa dà lọ bẹ obìnrin yìí wò nílé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú òun àti ìdílé rẹ̀. Ní báyìí, obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ ti lọ ń ṣèpàdé nílùú kan tó wà nítòsí, wọ́n sì tún ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nìṣó látorí tẹlifóònù.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa ní àwọn ọmọ abẹ́ títí “dé àwọn ìkángun ayé.” Àkànṣe ìwàásù tá a ṣe láwọn abúlé tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.​—Sáàmù 72:8.