Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 18, 2019
BRAZIL

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—São Paulo, Brazil

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—São Paulo, Brazil
  • Déètì: July 12 sí 14, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣe É: São Paulo Expo ní São Paulo, Brazil

  • Èdè: Èdè Adití ti Brazil, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Italian, Potogí, Sípáníìṣì

  • Àwọn Tó Wá: 36,624

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 291

  • Àwọn Tó Wá Láti Ìlẹ̀ Òkèèrè: 7,000

  • Áwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tó Wá: Àǹgólà, Ajẹntínà, Belgium, Czech-Slovak, Faransé, Ítálì, Mòsáńbíìkì, Pọ́túgà, Scandinavia, Suriname, Trinidad and Tobago, Amẹ́ríkà, Fẹnẹsúélà

  • Ìrírí: Maria Luiza Gonçalves ló máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe ń báwọn tó ń wá sí ọgbà ẹranko tó wà ní São Paulo Zoo sọ̀rọ̀. Nígbà tó ń kí àwọn tó wá sí àpéjọ káàbọ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ṣe nǹkan níbí ni mo ti bá pàdé. Jálẹ̀ ọdún ni wọ́n sì máa ń wá, àmọ́ tiyín yàtọ̀, mi ò tíì ráwọn tó pọ̀, síbẹ̀ tí wọ́n lọ́yàyà, tí wọ́n sì wà létòlétò bíi tiyín rí. Ẹ mà nífẹ̀ẹ́ ara yín ò! Ó hàn nínú bẹ́ ẹ ṣe ń gbáni mọ́ra, bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe síra yín àti nínú àwọn orin yín.”

 

Àwọn ará ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ ní pápákọ̀ òfúrufú São Paulo Guarulhos

Arákùnrin mẹ́rin láti São Paulo àti ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ní Brazil báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ káwọn èèyàn lè gbọ́ nípa àpéjọ àgbáyé tá a fẹ́ ṣe

Àwọn tó wá sí àpéjọ bá àwọn ará tó ń gbé ní São Paulo lọ sóde ẹ̀rí

Àwọn tó wá sí àpéjọ náà níta ibi tá a ti ṣe é lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà

Àwọn ará ń ṣàkọsílẹ̀ bí àpéjọ ṣe ń lọ lọ́wọ́

Arákùnrin Samuel Herd, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ Friday

Wọ́n ń ṣèrìbọmi fáwọn ará ní ọ̀sán ọjọ́ Sátidé àpéjọ náà

Àwọn arábìnrin ń túmọ̀ ohun tó ń lọ ní àpéjọ náà sí èdè tactile tó wà fáwọn tó fọ́jú tí wọ́n sì tún dití

Àwọn ará tó wá sí àpéjọ náà ń ya fọ́tò lóde

Àwọ́n tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti onírúrurú orílẹ̀-èdè ń juwọ́ sáwọn ará lọ́jọ́ tí àpéjọ náà parí