Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò àti ẹrẹ̀ tó ya ba nǹkan jẹ́ gan-an ní agbègbè tí òkè pọ̀ sí ní ìlú Petrópolis

FEBRUARY 23, 2022
BRAZIL

Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Òjò àti Ẹrẹ̀ Tó Ya Ṣọṣẹ́ ní Agbègbè Kan Lórílẹ̀-Èdè Brazil

Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Òjò àti Ẹrẹ̀ Tó Ya Ṣọṣẹ́ ní Agbègbè Kan Lórílẹ̀-Èdè Brazil

Ní February 15, 2022, òjò oníjì líle mú kí ẹrẹ̀ ya lágbègbè tí òkè pọ̀ sí ní ìlú Petrópolis ní ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, lórílẹ̀-èdè Brazil. Àjálù náà ba ọ̀pọ̀ ilé àti ilé iṣẹ́ jẹ́. Òjò yẹn pọ̀ gan-an kódà irú ẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ má rọ̀ rí lágbègbè náà.

Ìpalára Tí Àjálù Náà Ṣe Fáwọn Ará Wa

  • Arákùnrin kan fara pa gan-an, wọ́n sì gbé e lọ sílé ìwòsàn. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọmọ ẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì kú sínú ẹrẹ̀ náà

  • Arákùnrin kan náà kú

  • Akéde mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún (86) ló fi ilé wọn sílẹ̀

  • Ilé méjì ló wó pátápátá

  • Ilé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló bà jẹ́ díẹ̀

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ló bà jẹ́ díẹ̀

Bá A Ṣe Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́

  • Wọ́n yan Ìgbìmọ̀ To Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù kí wọ́n lè bójú tó ohun táwọn ará nílò

  • Alábòójútó àyíká àti àwọn alàgbà fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn ará nínú, bákan náà wọ́n pèsè oúnjẹ, omi àti aṣọ fún àwọn ará tí ọ̀rọ̀ kan

  • Àwọn ará tó fi ilé sílẹ̀ lọ ń gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí ọ̀dọ̀ àwọn ará míì fúngbà díẹ̀

  • Gbogbo àwọn ará tó ṣèrànwọ́ ni wọ́n tẹ̀ lé òfin tí ìjọba ṣe kí wọ́n lè dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àrùn Corona

Bá a ṣe ń rántí àwọn ará wa tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí yìí nínú àdúrà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ‘tu ọkàn wọn lára, á sì fìdí wọn múlẹ̀ gbọn-in,’ pàápàá àwọn tí èèyàn wọ́n kú.—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.