Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 4, 2020
BRAZIL

Àwọn Ará Wa Ṣèrànwọ́ Lẹ́yìn Tí Àkúnya Omi Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-èdè Brazil

Àwọn Ará Wa Ṣèrànwọ́ Lẹ́yìn Tí Àkúnya Omi Ṣọṣẹ́ Lórílẹ̀-èdè Brazil

Láti January 18, 2020 ni àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò ti ń rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Espírito Santo àti Minas Gerais lórílẹ̀-èdè Brazil, ìyẹn sì fa àkúnya omi tó lágbára gan-an. Omi tó ń ya wọnú ìlú ba ọ̀pọ̀ ilé jẹ́, ó gbé ọ̀pọ̀ ọkọ̀ lọ, ó sì hú àwọn igi dà nù. Àwọn aláṣẹ sọ pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti sá fi ilé wọn sílẹ̀, ó sì ju ọgọ́ta (60) èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Ìpínlẹ̀ Espírito Santo

Nílùú Iconha àti Alfredo Chaves, àkúnya omi náà ba ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án jẹ́, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ló sì ń gbébẹ̀. Inú wá dùn pé kò sí ará wa kankan tó fara pa tàbí tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti agbègbè yẹn ló yọ̀ǹda ara wọn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tí àkúnya omi náà ba ilé wọn jẹ́. Àwọn alàgbà bójú tó bí wọ́n ṣe pín oúnjẹ, omi àti aṣọ táwọn ará fi ṣètìlẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará tún ilé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn ṣe, títí kan ilé àwọn aládùúgbò tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìpínlẹ̀ Minas Gerais

Kò sí ará wa kankan tó fara pa tàbí tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àmọ́, Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún ló bà jẹ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta (50) ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sá kúrò nílé wọn. Àkúnya omi náà ká àwọn ará wa kan mọ́ débi pé ọkọ ojú omi ni wọ́n fi gbé wọn láti àjà kejì ilé wọn. Gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí àkúnya omi náà ba ilé wọn jẹ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì gbà sílé.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ní ìpínlẹ̀ Espírito Santo àti Minas Gerais, ìgbìmọ̀ yìí ló ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà bá. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù láwọn ìpínlẹ̀ yìí máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà láti pèsè ohun táwọn ará tí àjálù náà bá nílò nípa tara, kí wọ́n sì fi Bíbélì tù wọ́n nínú.

A ò ní jẹ́ kó sú wa láti máa gbàdúrà fáwọn ará tí àkúnya omi náà fìyà jẹ. A dúpẹ́ pé Jèhófà ń lo ẹgbẹ́ ará wa láti fún wọn lókun, láti tù wọ́n nínú àti láti máa pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò.​—Sáàmù 28:7.