Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 29, 2019
BRAZIL

Ìpàtẹ Ìkànnì JW.ORG Ṣàfihàn Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Fáwọn Odi Àtàwọn Afọ́jú Níbi Ìpàtẹ Ìwé Tó Wáyé Lórílẹ̀-èdè Brazil

Ìpàtẹ Ìkànnì JW.ORG Ṣàfihàn Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Fáwọn Odi Àtàwọn Afọ́jú Níbi Ìpàtẹ Ìwé Tó Wáyé Lórílẹ̀-èdè Brazil

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kópa nínú ìpàtẹ ìwé tó ń jẹ́ International Book Biennial of Rio de Janeiro tí wọ́n ṣe ní Riocentro Convention and Event Center láàárín August 30 sí September 8, 2019. Èyí ni àjọ̀dún tó tóbi jùlọ ní orílẹ̀-èdè Brazil. Oríṣiríṣi àwọn nǹkan tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ogún (520) ni wọ́n ṣe àfihàn ẹ̀, àwọn àlejò tó sì wá síbí ìpàtẹ náà jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600,000). Àwọn ará wa ṣe àtíbàbà kan tí wọ́n fi ṣàfihàn ìkànnì wa àti àwọn ohun tá à ń ṣe kó lè rọrùn fún gbogbo èèyàn láti rí àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì gbà. Láàárín ọjọ́ mẹ́wàá tí wọ́n fi ṣe ìpàtẹ náà, àwọn arákùnrin àti arábìnrin igba àti méjìdínlọ́gọ́ta (258) tó yọ̀ǹda ara wọn láti dúró níbi àtíbàbà náà pín ìtẹ̀jáde tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlógójì (3,737).

Lábẹ́ àtíbàbà yìí, a pàtẹ oríṣiríṣi àwọn nǹkan tá a dìídì ṣe fún àwọn àlejò tó jẹ́ odi, àwọn tí kò gbọ́rọ̀ dáadáa àti àwọn afọ́jú. Àwọn ará fi àwọn fídíò èdè adití ti Brazil (LIBRAS) han àwọn àlejò, àwọn akéde tó sì gbọ́ LIBRAS wà níbẹ̀ láti ran àwọn àlejò lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn níbẹ̀ sọ pé: “Bí àwọn èèyàn bá dé ibi àtíbàbà yìí, ara máa ń tù wọn láti bá wa sọ̀rọ̀, wọn kì í sì tijú. Ẹnì kan máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣàlàyé bí ìkànnì jw.org ṣe ń ṣiṣẹ́ àti ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wọn.”

Akéde kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá tó sì jẹ́ afọ́jú ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nípa bí ìwé tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fáwọn afọ́jú ṣe ràn án lọ́wọ́

Olùkọ́ kan wá síbi àtíbàbà wa pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méje tí wọ́n jẹ́ adití. Àwọn fídíò èdè adití tó wà lórí ìkànnì jw.org wú u lórí gan-an, pàápàá jù lọ àwọn fídíò tí wọ́n ṣe fáwọn ọ̀dọ́. Olùkọ́ náà ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn òbí máa ń bẹ òun láti bá àwọn ọmọ wọn tí wọ́n jẹ́ odi sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́. Olùkọ́ yìí ṣàlàyé pé òun á máa darí àwọn òbí sórí ìkànnì wa.

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa ń fi ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì han àlejò kan

A tún pàtẹ àwọn fídíò àti ìwé ní oríṣiríṣi èdè tó wà lórí ìkànnì jw.org bí èdè Guarani, Ticuna àti Xavante. Ricardo Carneiro tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò yẹn sọ pé: “Ohun tá a fẹ́ ni pé ká ran àwọn tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì ní èdè wọn.”

Àwọn tó ṣètò ìpàtẹ ìwé International Book Biennial of Rio de Janeiro fẹ́ kí àwọn ará Brazil máa fi ìwé kíkà kọ́ra kí ìgbésí-ayé wọn lè sunwọ̀n sí i. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àlejò tó wá síbí àtíbàbà jw.org ní wọ́n làǹfààní láti ka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde míì ní èdè wọn. Àwọn ìtẹ̀jáde yìí sì ti tún ayé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe láti àwọn ọdún yìí wá.​—2 Tímótì 3:16, 17.