FEBRUARY 12, 2019
BRAZIL
Ibi Tó Ń Gba Omi Dúró Ya Lulẹ̀ ní Brazil
Ní Friday, January 25, 2019, ibi tó ń gba omi dúró fáwọn tó ń wa kùsà ya lulẹ̀ ní ìlú Brumadinho, ìpínlẹ̀ Minas Gerais, lórílẹ̀-èdè Brazil, ó sì mú kí àbàtà tó pọ̀ gan-an ya wọ̀lú. Ó kéré tán àádọ́jọ (150) èèyàn ló kú, àwọn méjìlélọ́gọ́sàn-án (182) míì sì wà tí wọ́n ṣì ń wá títí di báyìí.
Ìjọ méjì ló wà ní ìlú Brumadinho, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ń lọ sí bí ọgọ́sàn-án (180), ilé iṣẹ́ tó ń wa kùsà náà sì ni púpọ̀ wọn ti ń ṣiṣẹ́. Àwọn arákùnrin mẹ́wàá ló ń ṣiṣẹ́ níbi tó ń gba omi dúró náà nígbà tó ya lulẹ̀. Mẹ́sàn-án lára wọn ò fara pa, àmọ́ ó dùn wá pé a ò tíì rí ẹnì kan tó kù tó jẹ́ alàgbà títí di báyìí. Yàtọ̀ síyẹn, ìdílé márùn-ún ó kéré tán ló ní láti kúrò ní ilé wọn, kódà ńṣe ni ọ̀kan lára àwọn ilé náà bà jẹ́ pátápátá.
Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Brazil àtàwọn alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè náà lọ wo àwọn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ sí, kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì pèsè ohun tí wọ́n nílò. Àdúrà wa ni pé kí Baba wa ọ̀run tu àwọn tí àjálù yìí kan nínú kó sì pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.—Róòmù 15:5.