DECEMBER 31, 2018
BRAZIL
Iná Ńlá Sọ Nílùú Manaus, ní Brazil
Láàárọ̀ kùtù December 18, iná sọ nínú ìlú Manaus lórílẹ̀-èdè Brazil, ó sì ba ó kéré tán ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ilé jẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò gbọ́ pé iná náà pa ẹnì kankan, àwọn mẹ́rin fara pa, ó sì lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) èèyàn tó ní láti kúrò níbi tí wọ́n ń gbé.
Ìròyìn tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Brazil fi hàn pé kò sí ìkankan lára àwọn ará tí iná náà pa tàbí tó ṣe léṣe. Àmọ́, ilé mẹ́wàá tó jẹ́ tàwọn ará wa ló bà jẹ́, ìyẹn sì mú kí akéde méjìdínlógún (18) pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kúrò níbi tí wọ́n ń gbé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀ kí wọ́n lè pèsè ohun táwọn akéde tí ọ̀rọ̀ náà kàn nílò.
Ó dá wa lójú pé àwọn ará wa tí ìjàǹbá iná yìí kàn ní Brazil kò ní jẹ́ kó sú wọn bí wọ́n ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ ‘ibi ààbò wa ní àkókò wàhálà.’—Sáàmù 9:9, 10.