Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 4, 2017
CENTRAL AFRICAN REPUBLIC

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Orílẹ̀-Èdè Central African Republic Sá Kúrò Nílùú Nítorí Ogun Abẹ́lé

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Orílẹ̀-Èdè Central African Republic Sá Kúrò Nílùú Nítorí Ogun Abẹ́lé

Ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tó ń pèsè ìrànwọ́ ń pín nǹkan fáwọn èèyàn.

DOUALA, lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù—Ìjà ẹ̀sìn àti ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó ń pọ̀ sí i ní àwọn apá kan lórílẹ̀-èdè Central African Republic ti mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sá lọ sí orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù àti Democratic Republic of Congo. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì tọ́jú wọn.

Lẹ́yìn tí ìjà bẹ̀rẹ̀ ní July 13, 2017, nǹkan bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] àti ìdílé kan pẹ̀lú ọmọ wọn jòjòló, sá lọ sí abúlé Mbai Mboum ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ìjà míì tún wáyé, àwọn jàǹdùkú bẹ̀rẹ̀ sí í dáná sunlé, nǹkan bí ọgọ́ta [60] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè Bangassou lórílẹ̀-èdè Central African Republic sá kúrò nílùú, wọ́n sá lọ sílùú Ndu lórílẹ̀-èdè Democratic Republic of Congo.

Ọmọ jòjòló lára àwon tó ń wá ibi isádi.

Jean-Bernard Fayanga tó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Central African Republic sọ pé: “Inú wa dùn pé kò sí ẹnì kankan nínú àwọn arákùnrin wa àti arábìnrin wa tó kú sínú ogun abẹ́lé náà. À ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Kamẹrúùnù àti Congo láti ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń pèsè ìrànwọ́ kí wọ́n lè pèsè omi tó dara, oúnjẹ, ibùgbé àti ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì fáwon Ẹlẹ́rìí náà.”

Àwọn alàgbà ṣètò láti pèsè ìrànwọ́ nípa tẹ̀mí, bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣètò láti wo àwon fídíò tó dá lórí Bíbélì, ní èdè Sango tó jẹ́ èdè ìbílé àwọn tó wá ibi ìsádi.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bójú tó ètò ìrànwọ́ láti oríléeṣẹ́ wa, ọrẹ táwọn èèyàn ń ṣe fún iṣẹ́ ìwàasù kárí ayé ni wọ́n sì ń lò.

Media Contacts:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Cameroon: Gilles Mba, +237-6996-30727

Central African Republic: Jean-Bernard Fayanga, +236-7575-1605