FEBRUARY 14, 2019
CUBA
Ìjì Líle Fa Àjálù Ńlá ní Cuba
Ní January 27, 2019, ìjì líle kan jà nílùú Havana tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Cuba. Ìjì náà lágbára gan-an (322 km/h), ó yára débi pé ó lè fa igi tu, kó sì gbé mọ́tò sọ nù. Kódà, òun ni ìjì tó lágbára jù lọ tó tíì jà nílùú yẹn láti bí ọgọ́rin (80) ọdún sẹ́yìn. Àwọn nǹkan tí ìjì náà bà jẹ́ ò lóǹkà, ọ̀pọ̀ ilé ló wó, ó sì fa omíyalé. Ó kéré tán, èèyàn mẹ́rin ló kú, àwọn ọgọ́rùn-méjì ó dín márùn-ún (195) sì fara pa.
Kò sí arákùnrin tàbí arábìnrin tó kú tàbí tó ṣèṣe nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Síbẹ̀, ilé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) tó jẹ́ tàwọn ará wa ni ìjì náà bà jẹ́, wọ́n sì máa ń lo mẹ́ta lára àwọn ilé náà fún ìpàdé. Ètò ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu láti ṣàtúnṣe ilé àwọn ará tí ìjì náà bà jẹ́.
Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ti ń pèsè ìrànwọ́ tẹ̀mí fáwọn ará tí àjálù yìí dé bá. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà tu àwọn ará yìí nínú kó sì fún wọn lókun kí wọ́n lè fara da àdánù ńlá yìí.—Nọ́ńbà 6:26.