Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 7, 2018
CUBA

Ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Kú Sínú Jàǹbá Ọkọ̀ Òfuurufú ní Cuba

Ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Kú Sínú Jàǹbá Ọkọ̀ Òfuurufú ní Cuba

Ní Friday, May 18, 2018, ọkọ̀ òfuurufú kan tí wọ́n ń pè ní Boeing 737 já bọ́ láìpẹ́ sígbà tó gbéra nílùú Havana lórílẹ̀-èdè Cuba. Nínú gbogbo àwọn mẹ́tàléláàádọ́fà (113) tó wọkọ̀ òfuurufú náà, ẹnì kan péré ló yè é. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú tó burú jù tó tíì wáyé lórílẹ̀-èdè yìí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Ó dùn wá pé ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́ta kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà (ìyẹn bàbá, ìyá àti ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún méjìlélógún (22)) wà lára àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. A ti sin òkú wọn ní Saturday, May 26, 2018.

Àwọn alàgbà tó wà nílùú náà ò fi tẹbí-tọ̀rẹ́ àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí sílẹ̀, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tù wọ́n nínú. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn aláṣẹ ìlú ń fìfẹ́ ṣèrànwọ́. Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní yéé ‘tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú’ lásìkò tí nǹkan nira yìí.​—Aísáyà 61:1, 2.