JULY 19, 2019
DENMARK
Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Nínú Ìtàn Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: A Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki Jáde Ní Èdè Icelandic
Ní July 19, 2019, Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi tayọ̀tayọ̀ mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lèdè Icelandic ní àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní Copenhagen lórílẹ̀ èdè Denmark.
Lówùúrọ̀ Friday àpéjọ náà, alága sọ pé kí gbogbo àwọn tó wà làwọn ìjọ tó ń sọ èdè Icelandic wá sí yàrá kékeré kan tó wà nínú pápá ìṣeré náà ní àkókò ìsinmi ọ̀sán. Níbi àkànṣe ìpàdé yìí ni Arákùnrin Lett ti fún àwọn ọgọ́rùn mẹ́ta àti mọ́kànlélógójì (341) arákùnrin àti arábìnrin tó wà níbẹ̀, tí wọn sì gbà á pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ọmọ ìlú Iceland ti ṣiṣẹ́ láti tú Bíbélì sí èdè wọn. Ní ọdún 1540, Oddur Gottskálksson tẹ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì jáde ní èdè Iceland fún ìgbà àkọ́kọ́. Láti ọdún 2010 ni àwọn ará wa tó ń sọ èdè Icelandic ti ń lo Bíbélì tó ń jẹ́ Bible of the 21st Century èyí tí àjọ Icelandic Bible Company tẹ̀ jáde. Ní báyìí, ara àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń gbé lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Icelandic ti wà lọ́nà láti lo Bíbélì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí láti sọ ìròyìn ayọ̀ náà fún àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) tó ń sọ èdè yìí.
Arákùnrin kan tó jẹ́ ọkàn lára àwọn tó ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ náà sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbà tó ọdún mẹ́rin láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì sí èdè Icelandic. Ohun tó mú kí ìtumọ̀ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé, ó dá orúkọ Jèhófà pa dà sí gbogbo ibi tó yẹ kó wà nínú Ìwé Mímọ́. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Jésù tó wà ní Jòhánù 17:26 tó sọ pé: ‘Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.’”
A dúpẹ́ pé Jèhófà ń bá a lọ láti bù kún iṣẹ́ tó gbé fún wa láti wàásù ìhìn rere dé gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé pátá. Bá a ṣe ń túmọ̀ Bíbélì ti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí yanjú. Àdúrà wa ni pé kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run” bí wọ́n ṣe ń ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní èdè ìbílẹ̀ wọn.—Ìṣe 2:11.