APRIL 23, 2020
ECUADOR
Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Ecuador Ń Wàásù Fáwọn Èèyàn Láì Kúrò Nílé
Ibi gbogbo láyé làwọn ará wa ti ń lo àwọn ọ̀nà míì láti máa wàásù nítorí àrùn COVID-19 tí kò jẹ́ kí wọ́n lè máa wàásù bí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àwọn ará wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Ecuador ń lo onírúurú ọ̀nà láti wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀dọ́bìnrin ọlọ́dún méje kan tó ń gbé ní ìlú Ambato. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ màmá rẹ̀, ó kọ àtẹ̀jíṣẹ́, ó sì fi ránṣẹ́ sáwọn tíṣà ilé ìwé rẹ̀. Lára ohun tó kọ nìyí: “Ẹ káàárọ̀. Mò fi àtèjíṣẹ́ yìí ránṣẹ́ sí yín láti tù yín nínú nítorí pé àsìkò tá a wà yìí nira gan-an. Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ nínú ìwé Ìfihàn 21:4 pé ọ̀la máa dáa. Ìlujá tí mo fi ránṣẹ́ máa gbé yín lọ síbi tẹ́ ẹ ti máa rí àlàyé tó pọ̀ sí i.”
Ọ̀kan lára àwọn tíṣà rẹ̀ dá èsì pa dà, ó ní: “O ṣeun gan-an ni, ọmọ dáadáa. Ọmọdé ni ẹ́, àmọ́ ọ̀rọ̀ tó o sọ yìí mọ́gbọ́n dání gan-an.” Ẹlòmíì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gan-an, ó sì béèrè bóyá òun lè rí Ìwé Ìtàn Bíbélì, èyí tó wà lórí ẹ̀rọ. Ó sọ fún ọmọ náà pé òun ní ìwé yẹn tẹ́lẹ̀ àmọ́ òun yá ọmọ iléèwé kan. Ọ̀dọ́bìnrin náà wá ṣàlàyé fún tíṣà yẹn pé ó lè rí ìwé náà lórí ìkànnì jw.org.
Àpẹẹrẹ míì ni tọkọtaya kan tó ń gbé nílùú Quevedo. Wọ́n wá orúkọ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórí fóònù wọn, wọ́n sì fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí wọn. Ohun tí wọ́n sọ rèé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Kò ṣeé ṣe fún wa láti máa wàásù láti ilé dé ilé bá a ti máa ń ṣe nítorí àrùn tó ń jà ràn-ìn nílẹ̀ wa àti kárí ayé. Síbẹ̀, inú wa máa dùn tá a bá lè bá yín sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.”
Ọ̀pọ̀ ló gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Obìnrin kan tí kì í gbà káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá òun sọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbóríyìn fáwọn tọkọtaya náà pé òun mọrírì bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti tu àwọn èèyàn nínú. Ó sọ fún wọn pé ọ̀kan òun ò balẹ̀ nítorí ìṣòro tó gbòde kan yìí. Ni tọkọtaya náà bá fi ìwé ìròyìn wa kan ránṣẹ́ sí i, ìyẹn Jí!, No. 1 2020, tó ní àkòrí náà, “Bó O Ṣe Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn.” Nígbà tí wọ́n tún jọ ráyè sọ̀rọ̀, obìnrin náà sọ pé òun gbádùn ìwé náà gan-an, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti ka ìwé náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Àpẹẹrẹ ẹlòmíì ni arábìnrin adití kan tó ń jẹ́ Johana tó ń gbé ní Santo Domingo de los Tsáchilas. Arábìnrin yìí fi àwòrán * “kọ̀wé” sáwọn èèyàn. Lọ́nà wo? Ó fọwọ́ ya onírúuru àwòrán, ó ya fọ́tò àwọn àwòrán náà, ó sì fi í ránṣẹ́ sáwọn ojúlùmọ̀ ẹ̀ tó jẹ́ adití. Àmọ́, obìnrin kan tí kì í ṣe adití wà lára àwọn tó fi àtẹ̀jíṣẹ́ náà ránṣẹ́ sí. Kò pẹ́ tí obìnrin yẹn rí àtẹ̀jíṣẹ́ náà gbà ló fèsì pa dà, tó sì ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Àmọ́ Johana ò lóyé àwọn ìbéèrè yẹn, torí náà ó sọ fún arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tí kì í ṣe adití tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rhonda pé kó dáhùn àwọn ìbèérè obìnrin náà.
Obìnrin yẹn sọ fún Arábìnrin Rhonda pé àwọn àwòrán tí Johana fi ránṣẹ́ sí òun ya òun lẹ́nu gan-an. Ó wá béèrè bóyá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tún wà tó ṣàlàyé ìdí táwọn nǹkan burúkú fi ń ṣẹ̀lẹ̀ láyé. Arábìnrin Rhonda ka Lúùkù 21:10, 11 fún un, ó sì fi ìlujá fídíò Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà? àti Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? ránṣẹ́ sí i. Obìnrin náà sọ pé òun á fẹ́ káwọn tún jọ sọ̀rọ̀ Bíbélì nígbà míì.
Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí kò dẹ́kun àtimáa “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run” bó tiẹ̀ wà lẹ́wọ̀n, àwọn ará wa náà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa wàásù báwọn náà ò tiẹ̀ lè jáde nílé.—Ìṣe 28:23.
^ ìpínrọ̀ 7 Ọ̀pọ̀ àwọn adití ló máa ń ṣòro fún láti lóyé ìwé téèyàn bá kọ, torí náà dípò káwọn ará wa tó gbọ́ èdè adití kọ̀wẹ́ sílẹ̀ fún ẹni tó jẹ́ adití, àwòrán ni wọ́n sábà máa ń yà láti fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fẹ́ni tó jẹ́ adití.