Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 7, 2017
EGYPT

‘Mò Ń Retí Ìgbà tí Wọn Ò Ní Fòfin Dè Wá Láìtọ́ Mọ́

‘Mò Ń Retí Ìgbà tí Wọn Ò Ní Fòfin Dè Wá Láìtọ́ Mọ́

Ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì ni Ehab Samir, ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta [52] ni, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Ìjọba orílẹ̀-èdè Íjíbítì ń fúngun mọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn wọn, Ọ̀gbẹ́ni Samir sì sọ pé èyí ti mú kí àwọn aláṣẹ máa ṣe ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “bíi pé wọ́n jẹ́ ọ̀daràn.” Inú ẹ̀ wá dùn nígbà tó ka àpilẹ̀kọ kan lórí ìkànnì tó jẹ́rìí sí i pé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an nìyẹn.

Àkòrí àpilẹ̀kọ náà ni “Ohun tí Dr. Riham Atef Kọ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” August 19, 2016 ni iléeṣẹ́ Shbab Misr gbé e jáde lórí ìkànnì lórílẹ̀-èdè Íjíbítì. Dr. Atef, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ní University of Cairo, tó sì tún jẹ́ oníròyìn, sọ pé òun ò fara mọ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ Íjíbítì ṣe ṣi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóye. Ó mọ àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lẹ́yìn tó sì ṣèwádìí dáadáa nípa wọn, ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé èèyàn dáadáa ni wọ́n, wọ́n sì gbà pé àwọn míì lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́.”

“Èèyàn Àlàáfíà Ni Wọ́n, Wọ́n sì Máa Ń Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ẹlòmíì”

Dr. Atef sọ pé àwọn tí òun tìtorí wọn kọ àpilẹ̀kọ yẹn ni “àwọn tí kò mọ nǹkan kan nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn tó kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ohun tí kò jóòótọ́ tí wọ́n gbọ́ nípa wọn.” Nínú àpilẹ̀kọ tó kọ, ó ṣe àlàyé ṣókí nípa àwọn ohun táwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́, ó sì sọ pé “ọ̀pọ̀ ìsọfúnni ló wà lórí ìkànnì wọn, ìyẹn www.pr418.com.”

Lẹ́yìn tí Dr. Atef fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó rí i pé irú ẹni tí wọ́n jẹ́ yàtọ̀ pátápátá sí ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wò wọ́n nílẹ̀ Íjíbítì. Ó sọ pé: “Mi ò mọ ìdí tí wọ́n fi fòfin dè wọ́n. Wọn kì í dá sí òṣèlú. . . . Èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, wọ́n sì máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì.” Dr. Atef sọ ohun tó máa mú kí àwọn tó bá ka àpilẹ̀kọ náà tún ọ̀rọ̀ ọ̀hún rò, ó ní: “Ṣé torí ìyẹn ni ìjọba ṣe fòfin dè wọ́n? Àbí torí pé ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni látinú Bíbélì yàtọ̀ sí ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ àwọn èèyàn ni ìjọba ṣe fòfin dè wọ́n?”

‘Mò Ń Retí Ìgbà tí Wọn Ò Ní Fòfin Dè Wá Mọ́’

Ọ̀gbẹ́ni Samir gbádùn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn débi pé kò lè pa ayọ̀ ẹ̀ mọ́ra, ó wò ó pé àfi kóun kọ lẹ́tà ìmọrírì sí àwọn tó gbé ìròyìn náà jáde. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ ni mo ti kà nínú ìròyìn [ilẹ̀ Íjíbítì] nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ èyí tó sọ̀rọ̀ wọn dáadáa ò pọ̀. Torí náà, mo yin Dr. Riham Atef torí pé ó fìgboyà sọ òótọ́.” Iléeṣẹ́ ìròyìn náà gbé ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Samir sọ jáde lórí ìkànnì ní December 11, 2016.

Nínú lẹ́tà tí Ọ̀gbẹ́ni Samir kọ, ó ṣàlàyé pé bí wọ́n ṣe ń hùwà àìdáa sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìtọ́ yìí ò múnú òun dùn rárá, ó sì sọ pé irọ́ táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń gbé kiri nípa wọn ló fà á. Ọ̀gbẹ́ni Samir sọ pé irọ́ tí wọ́n ń gbé kiri yìí gan-an ló mú kí àwọn kan hùwà àìdáa sí òun fúnra òun. Ó wá sọ pé: “Téèyàn bá fẹ́ mọ ẹnì kan dáadáa, ohun tó dáa jù kó ṣe ni pé kóun àti ẹni yẹn jọ ríra sọ̀rọ̀. Torí náà, mò ń fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ Dr. Riham Atef fún àpilẹ̀kọ tó kọ.”

Ọ̀rọ̀ tó ń mórí ẹni wú yìí ni Ọ̀gbẹ́ni Samir fi parí lẹ́tà rẹ̀, ó ní: “Mò ń retí ìgbà tí wọn ò ní fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìtọ́ mọ́, tí wọ́n á jẹ́ ká lómìnira láti máa ṣe ìjọsìn wa fàlàlà lórílẹ̀-èdè wa.”

Wọ́n Ń Retí Ìgbà tí Wọ́n Máa Lómìnira Ẹ̀sìn

Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira ẹ̀sìn ní Íjíbítì, ìjọba sì forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àmọ́ lọ́dún 1960, wọ́n fòfin dè wọ́n, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn ṣọ́ọ̀ṣì míì lẹ́tọ̀ọ́ sí ní Íjíbítì, kódà, wọ́n fi àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn wọn dù wọ́n.

Bíi ti àtẹ̀yìnwá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Íjíbítì ń bá a lọ láti ṣe ohun tó fi hàn pé “èèyàn àlàáfíà” làwọn jẹ́ láwùjọ, pé àwọn “nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì” ní gbogbo ọ̀nà, wọn ò sì yíwà pa dà, bí Dr. Atef náà ṣe jẹ́rìí sí i. Bíi ti Ọ̀gbẹ́ni Samir, ọ̀pọ̀ àwọn míì ló ń retí ìgbà tí wọn ò ní fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn Ẹlẹ́rìí ní dù wọ́n mọ́, tí wọ́n á sì pa dà lómìnira ẹ̀sìn ní Íjíbítì.