Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 4, 2020
ERITREA

Wọ́n Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjìdínlọ́gbọ̀n (28) Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè Eritrea

Wọ́n Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjìdínlọ́gbọ̀n (28) Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè Eritrea

Ní December 4, 2020, wọ́n dá arákùnrin mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) àti arábìnrin méjì sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Eritrea. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti lo ọdún márùn-ún sí mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé ló ń bá wọn yọ̀ pé wọ́n tú wọn sílẹ̀. Bákan náà, a ò ní dákẹ́ àdúrà lórí àwọn mẹ́rìnlélógún (24) tó kù sẹ́wọ̀n ní Eritrea.​—Ìṣe 12:5.