Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 13, 2019
ETIÓPÍÀ

Arábìnrin Kan Kú Nínú Jàǹbá Ọkọ̀ Òfúrufú Ethiopian Airlines

Arábìnrin Kan Kú Nínú Jàǹbá Ọkọ̀ Òfúrufú Ethiopian Airlines

Ní Sunday, March 10, ọkọ̀ òfúrufú 302 ti Ethiopian Airlines gbéra ní Addis Ababa tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Etiópíà, àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn tó gbéra tó fi ko jàǹbá. Gbogbo àwọn mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ (157) tó wà nínú ẹ̀ ló sì kú.

Ó dùn wá pé arábìnrin wa kan tó ń jẹ́ Rosemary Mumbi wà lára àwọn tó kú nínú jàǹbá ọkọ̀ náà. Ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ni Arábìnrin Mumbi, ó sì máa ń lo èyí tó pọ̀ jù lára àkókò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìjọ Roma Manzoni Inglese ló wà ní ìlú Rome, lórílẹ̀-èdè Ítálì.

Ìròyìn ikú arábìnrin yìí dùn wá gan-an. À ń retí ìgbà tí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa jíǹde, tí àá sì lè kí wọn káàbọ̀ títí kan Arábìnrin Mumbi.—Ìfihàn 20:13.