Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 8, 2019
FARANSÉ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019​—⁠Paris, France

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019​—⁠Paris, France
  • Déètì: August 2-4, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣe É: Parc des Expositions de Paris-Nord Villepinte ní Paris, France

  • Èdè: English, French, German, Romanian, Russian, Spanish

  • Àwọn Tó Wá: 37,809

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 265

  • Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 5,500

  • Àwọn Ẹ̀ka Táa Pè: Britain, Canada, Central Europe, Chile, Côte dʹIvoire, Ecuador, Greece, Kazakhstan, Moldova, New Caledonia, Tahiti, United States, Zambia

  • Ìrírí: Bí ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó ibi tá a ti ṣe àpéjọ yẹn ṣe rí sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ torí bí iye ọkọ̀ tó wà níbẹ̀ ṣe pọ̀, ó ní: “Ṣẹ́yin kì í bínú ni? Ní gbogbo ìgbà tì ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ṣe àpéjọ yín, ẹ̀ ò bá ara yín jà, kò sẹ́ni tó fi fèrè ọkọ̀ pariwo mọ́ àwọn míì, kò sẹ́ni tínú ń bí, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó sáré wọ iwájú ọkọ̀ míì.”

    Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì tí àwọn tó wá dé sí sọ pé: “Mo ti rí oríṣiríṣi àwùjọ àwọn èèyàn, àmọ́ ètò yín ló dáa jù lọ. Ṣe ninú àwọn èèyàn kàn ń dùn tí ara sì tù wọ́n!”

 

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnnrin ń kí àwọn tó wá káàbọ̀ sí Paris ní pápákọ̀ òfuurufú

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń wàásù níbi térò pọ̀ sí; Eiffel Tower táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó ló wà lẹ́yìn yẹn

Àwọn ará ń kí ara wọn ní ìta ibi àpéjọ náà

Tọkọtaya kan jọ ṣèrìbọmi lọ́jọ́ Sátidé

Àwọn ará tó wá láti Tahiti tó wọ aṣọ ìbílẹ̀ wọ́n ń tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ olùdarí ló sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ Sátidé

Ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán ń fi àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún tó wá sí àpéjọ náà hàn bí wọ́n ṣe ń juwọ́ sí àwọn ará ní ìparí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday

Arákùnrin kan ń fi bí wọ́n ṣe ń fi ìyẹ̀fun ṣe àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ Faransé hàn ní Bẹ́tẹ́lì