Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 29, 2018
FARANSÉ

Omíyalé ní Gúúsù Ilẹ̀ Faransé

Omíyalé ní Gúúsù Ilẹ̀ Faransé

Òjò tó rọ̀ ní October 14 àti 15, 2018 pọ̀ gan-an láwọn agbègbè gúúsù ilẹ̀ Faransé, ó sì fa omíyalé tó gbẹ̀mí ó kéré tán, èèyàn mẹ́wàá.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Faransé sọ pé àlàáfíà ni gbogbo àwọn ará tó ń gbé lágbègbè náà wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti kó àwọn ìdílé kan kúrò níbi tí wọ́n ń gbé torí omíyalé. Àwọn ará kan sọ bí omíyalé náà ṣe kàn wọ́n, wọ́n ní ó ba àwọn nǹkan wọn jẹ́ díẹ̀, kódà àwọn ilé mẹ́ta kan wà tó bà jẹ́. Ẹ̀ka Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sì ti ń pèsè ohun táwọn ará nílò fún wọn.

Ó dá wa lójú pé ọwọ́ agbára Ọlọ́run wa, Jèhófà, máa ‘di àwọn ará wa mú ṣinṣin’ bí wọ́n ṣe rọ̀ mọ́ ọn lásìkò wàhálà yìí.—Sáàmù 63:8.