Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 4, 2017
FINLAND

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tu Àwọn Èèyàn Nínú lẹ́yìn Ìpànìyàn tó wáyé nílùú Turku, lórílẹ̀-èdè Finland

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tu Àwọn Èèyàn Nínú lẹ́yìn Ìpànìyàn tó wáyé nílùú Turku, lórílẹ̀-èdè Finland

HELSINKI—Ní ọ̀ṣán Friday, August 18, 2017, afẹ̀míṣòfò kan pa ọ̀kan nínú àwon arábìnrin wa ní orílẹ̀-èdè Finland. Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé àwọn obìnrin ni afẹ̀míṣòfò yìí dájú sọ. Yàtọ̀ sí arábìnrin wa, afẹ̀míṣòfò yẹn tún pa obìnrin kan, ó sì ṣe èèyàn mẹ́jọ léṣe ní gbàgede ọjà ìlú Turku tó wà ní etíkun orílẹ̀-èdè Finland. Ẹsẹ̀kẹsè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ni àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Finland, alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà lọ pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn, wọ́n sì tù wọ́n nínú.

Veikko Leinonen tó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Finland, sọ pé: “Nǹkan burúkú gbáà ni ohun to ṣẹlẹ̀ yìí, ó sì bà wá nínú jẹ́ gan-an pé ọ̀kan lára arábìnrin wa tó jẹ́ aṣáájú ònà kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà níbi tó ti ń wàásù níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí. Èèyàn lè gbìyànjú láti sá fún ewu, ṣùgbọ́n nígbà míì èèyàn lè ṣe kòńgẹ́ ‘ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,’ títí kan ọṣẹ́ táwọn àfẹ̀míṣòfò máa ń ṣe. Síbẹ̀, àá máa báa lọ láti tu ara wa nínú lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá ìdílé arábìnrin tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú, kó sì fún wọn ní àláàfíà rẹ̀. Àá máa bá a lọ láti wà lójúfò, àá sì máa ṣọ́ra, síbẹ̀ a ò ní jẹ́ kí ìbẹ̀rù bò wá mọ́lẹ̀, àá sì máa fìtara wàásù nìṣó.”—Oníwàásù 9:11; Róòmù 15:13; Fílípì 4:6, 7.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tún kọ lẹ́tà sí gbogbo àwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè Finland láti tu àwọn ará nínú. Láfikún sí èyí, ẹ̀ka ọ́fììsì tún ṣètò ìpàdé àkànṣe láti pèsè ìṣírí fún nǹkan bí 135 arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń ìwàásù níbi tí èrò pọ̀ sí ní Turku. Àwọn aṣáájú ọ̀nà yìí fi hàn pé àwọn jẹ́ onígboyà bí wọ́n ṣe pinnu pé àwọn á máa wàásù nìṣó níbi tí èrò pọ̀ sí.

Ẹ̀rù ba ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé ní Turku gan-an torí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìdí sì ni pé wọ́n gbà pé orílẹ̀-èdè Finland jẹ́ ọ̀kan lára orílẹ̀-èdè tó ní ààbò jù lọ. Láàrọ̀ ọjọ́ kẹjì tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ńṣe làwọn ará ń bá ìwàásù wọn lọ láti ilé-dé-ilé. Wọ́n ń tu àwọn èèyàn nínú, wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Finland dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé fún àdúrà yín àti ìtìlẹ́yìn yín. (1 Pétérù 2:17; 5:9) Àmọ́ ọpẹ́ wa tó ga jù lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú.”—Róòmù 15:5.

Media Contacts:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Finland: Veikko Leinonen, +358-400-453-020