NOVEMBER 27, 2019
GÁNÀ
A Mú Odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Nzema
Lẹ́yìn odindi ọdún mẹ́rin táwọn atúmọ̀ èdè fi ṣiṣẹ́, a mú odindi Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Nzema ní November 22, 2019, ní àpéjọ àgbègbè tó wáyé nílùú Bawia, ní apá ìwọ̀-òòrùn orílẹ̀-èdè Ghana. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti mọ́kànléláàádọ́ta (3,051) ló pésẹ̀ nígbà tí Arákùnrin Samuel M. Kwesie, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀-ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Ghana mú Bíbélì náà jáde.
Àwọn atúmọ̀ èdè méje ló para pọ̀ ṣé iṣẹ́ yìí. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun yìí rọrùn gan an, ìyẹn sì jẹ́ kó lè yé gbogbo àwọn tó ń kà á, títí kan àwọn ọmọdé. Èyí á mú kí àwọn tó ń kà á túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Baba wọn ọ̀run.”
Bíbélì tí àjọ Bible Society of Ghana tẹ̀ jáde làwọn ará tó ń sọ èdè Nzema ń lò tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ìtumọ̀ Bíbélì yìí yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò, ó sì tún ṣòro lóye. Yàtọ̀ síyẹn, bí Bíbélì ṣe wọ́n lórílẹ̀-èdè Ghana mú kó ṣòro fáwọn ará kan láti ní tiwọn.
Àmọ́, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Nzema yìí lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, ó rọrùn láti lóye, àwọn èèyàn sì lè gbà á lọ́fẹ̀ẹ́. Bíbélì yìí máa ṣàǹfààní fáwọn akéde tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìlélọ́gbọ̀n (1,532) tó ń sọ èdè Nzema tí wọ́n sì ń wàásù fáwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgbọ̀n (330,000) tí wọ́n ń sọ èdè náà lórílẹ̀-èdè Ghana.
Àdúrà wa ni pé, kí ìtumọ̀ Bíbélì yìí mú kí àwọn ará wa máa ní inú dídùn nínú “òfin Jèhófà.”—Sáàmù 1:1, 2.