Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 11, 2019
GÍRÍÌSÌ

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Athens ní Gíríìsì

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Athens ní Gíríìsì
  • Déètì: July 5 sí 7, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣe É: Pápá ìṣeré Athens Olympic Stadium ní ìlú Athens, Greece

  • Èdè: Albanian, Gẹ̀ẹ́sì, Gíríìkì, Èdè Adití ti Gíríìkì, Romany (ti Gúúsù Greece), Russian

  • Àwọn Tó Wá: 36,873

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 406

  • Àwọn Tó Wá Láti Ìlẹ̀ Òkèèrè: 6,000

  • Áwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tó Wá: Alibéníà, Àméníà, Australasia, Bọ̀géríà, Central America, Central Europe, Fíjì, Japan, Kyrgyzstan, North Macedonia, Tọ́kì, Amẹ́rikà

  • Ìrírí: Òṣìṣẹ́ kan tọ́ máa ń ṣètó ìrìn àjò sọ pé: “Látìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ síṣètò ìrìn àjò, mí ò tíì rí ibikíbi láyé tí wọ́n ti ń ṣètò tó dáà bí eléyìí, kí wọ́n sì tún bójú tó àwọn arìnrìn àjò. Ńṣe ni mò ń wò yín lánàá, ẹ wú mi lórí gan-an! Ẹ ṣètò ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600) arìnrìn àjò láàárìn wákàtí díẹ̀ lọ́nà tó dáa ju ti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ. Èyí tó wú mi lórí jù ni ẹ̀rín músẹ́ tó wà lójú yín. Kí n sọ̀ótọ́, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí, mo sì máa ń mọ̀ tẹ́nì kan bá ń rẹ́rìn-ín látọkàn wá tàbí tó bá jẹ́ pé ẹ̀rín ẹ̀ ò dọ́kàn. Àmọ́, gbogbo yín lẹ̀ ń rẹ́rìn-ín látọkàn.”

 

Díẹ̀ lára àwọn 4,000 tó yọ̀ǹda ara wọn láti mú kí pápá ìṣeré tí wọ́n fẹ́ lò wà ní sẹpẹ́ fún àpéjọ náà

Àwọn ọ̀dọ́ yìí ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí orílẹ̀-èdè Gíríìsì

Ọ̀kan lára àwọn ẹni tuntun ń ṣèrìbọmi

Àwọn arábìnrin tó wà lápá ibi tí wọ́n ti sọ èdè Romany níbi àpéjọ náà ń ya fọ́tò. Èyí nìgbà àkọ́kọ́ tí èdè Romany máa wà lára àwọn èdè tí wọ́n lò fún àpéjọ àgbáyé tó wáyé ní Gíríìsì

Àwọn ará tó ń gbé níbẹ̀ bá àwọn tó wá sí àpéjọ lọ sóde ẹ̀rí

Àwọn ará lọ wo àwókù Gíríìsì àtijọ́

Nígbà àpèjẹ tí wọ́n ṣe lálẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n ṣe eré ìtàn Bíbélì tó dá lórí iṣẹ́ ìwáásù tí Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ní Gíríìsì

Àwọn ará yìí ń jó ijó tí wọ́n pè ní Syrtaki láti fi dá àwọn àlejò lára yá

Arábìnrin yìí ń ta bouzouki, ó dà bíi gìtá ìbílẹ̀ àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì

Àwọn ará tí wọ́n jẹ́ àlejò ń kọ́ èdè Gíríìkì

Arákùnrin David Splane, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ tí àpéjọ náà parí

Àwọ́n tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè ń juwọ́ sáwọn ará lọ́jọ́ tí àpéjọ parí