Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Minos Kokkinakis: Ohun nìyẹn lọ́wọ́ ẹ̀yìn pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiẹ̀ nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn. Lọ́wọ́ iwájú, nígbà tó di àgbàlagbà.

JANUARY 7, 2019
GÍRÍÌSÌ

Ìtàn Mánigbàgbé: A fi Odindi Àádọ́ta Ọdún Jà fún Ẹ̀tọ́ Tá A Ní Láti Wàásù

Ìtàn Mánigbàgbé: A fi Odindi Àádọ́ta Ọdún Jà fún Ẹ̀tọ́ Tá A Ní Láti Wàásù

Ọjọ́ ọ̀hún rèé bí àná, ìyẹn ní ọgọ́rin (80) ọdún sẹ́yìn, nígbà tí ìjọba gbé Arákùnrin Minos Kokkinakis wọ̀ọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi máa ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Lọkọ̀ náà bá forí lé erékùṣù kan tí wọ́n ń pè ní Amorgós láàárín agbami òkun Aegean Sea, lórílẹ̀-èdè Gíríìsì. Ìgbèkùn yẹn ni Arákùnrin Minos Kokkinakis wà fún odindi ọdún kan àti oṣù kan. Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ilé ẹjọ́ kan ló dá a lẹ́bi pé ó rú òfin tó ní káwọn èèyàn má ṣe bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ilé ẹjọ́ ò sì gbọ́ tẹ́nu ẹ̀ kí wọ́n tó dá a lẹ́bi. Eré la pè é, bí ìjọba ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í nawọ́ gán àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn o. Láàárín ọdún 1938 sí 1992, wọ́n mú ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún, ọgọ́rùn-ún kan ó lè mẹ́tàdínláàádọ́ta (19,147) àwọn ará wa. Wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n rú òfin tí Ioannis Metaxas tó jẹ́ aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ lórílẹ̀-èdè Gíríìsì ṣe. Láwọn ọdún yẹn, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ò dẹ́kun àtimáa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bí ìjọba tiẹ̀ ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n ń mú wọn, tí wọ́n sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n.

Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Arákùnrinr Kokkinakis nígbà tọ́rọ̀ yìí wáyé, àtìgbà yẹn náà ló ti ń jà fún ẹ̀tọ́ tó ní láti wàásù, odindi àádọ́ta (50) ló sì fi ja ìjà yìí. Ó lè ní ọgọ́ta (60) ìgbà tí wọ́n mú un, ó sì lé lọ́dún mẹ́fà tó lò lẹ́wọ̀n àti láwọn erékùṣù tí wọ́n ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n sí. Wọ́n fi ojú òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì rí màbo ní gbogbo àsìkò yẹn. Wọ́n tún mú un nígbà tó pé ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77). Ó pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àmọ́ ilé ẹjọ́ kò gba tiẹ̀ rò, ló bá gbọ́rọ̀ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Gíríìsì. Nígbà táwọn yẹn tún da ẹjọ́ ẹ̀ nù, Arákùnrin Kokkinakis gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR), pé orílẹ̀-èdè Gíríìsì ń fi ẹ̀tọ́ òun du òun bí wọn ò ṣe jẹ́ kóun sin Ọlọ́run bó ṣe fẹ́. Nígbà tí ilé ẹjọ́ yẹn máa kéde ìdájọ́ wọn lọ́dún 1993, ṣe ni wọ́n dá Arákùnrin Minos Kokkinakis, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) láre. Mánigbàgbé ni ìdájọ́ yẹn, torí pé ìyẹn ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR máa dá ìjọba orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lẹ́bi pé wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n, pé wọn ò jẹ́ kí wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run fàlàlà. * Ẹ wá rídìí tá a fi ń dáwọ̀ọ́ ìdùnnú, torí pé ọdún 2018 ló pé ọdún kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tá a jagunmólú ẹjọ́ yẹn. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ọ̀mọ̀wé kan tó mọ tìfuntẹ̀dọ̀ nípa ọ̀ràn òfin sọ? Ó ní ẹjọ́ Kokkinakis “jẹ́ ògúnnágbòǹgbò táwọn amòfin máa ń tọ́ka sí lára àwọn ìgbẹ́jọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù bójú tó lórí ọ̀ràn jíjà fún ẹ̀tọ́ ẹni tó bá kan ọ̀ràn ìsìn.”

Àpẹẹrẹ ni ẹjọ́ Kokkinakis á máa jẹ́ nígbàkigbà, pàápàá lásìkò tàwọn ìjọba orílẹ̀-èdè alágbára, bíi Rọ́ṣíà, ń fẹ̀tọ́ àwọn èèyàn Jèhófà dù wọ́n, tí wọ́n ò jẹ́ kí wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run wọn bó ṣe fẹ́.

Àwa èèyàn Jèhófà níbi gbogbo láyé mọyì bí Arákùrin Kokkinakis ṣe ní ìgbàgbọ́, tí kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣí òun lọ́wọ́ wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ gidi nìyẹn jẹ́ fáwọn tó kojú àtakò àti inúnibíni lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A ò jẹ́ gbàgbé ìtara rẹ̀ àti bó ṣe di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú ṣinṣin lójú inúnibíni.—Róòmù 1:8.

^ ìpínrọ̀ 3 Minos Kokkinakis kú ní January 1999.