Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 27, 2018
GÍRÍÌSÌ

Iná Sọ Nínú Igbó Nílẹ̀ Gíríìsì

Iná Sọ Nínú Igbó Nílẹ̀ Gíríìsì

Lẹ́yìn òde ìlú Athens nílẹ̀ Gíríìsì, iná sọ nínú igbó, atẹ́gùn líle sì mú kó túbọ̀ ràn bí iná ọyẹ́. Iná yìí ṣèpalára fáwọn èèyàn, ó sì ba nǹkan jẹ́. Ó kéré tán, èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76) ni ẹ̀mí wọn lọ sí i, àwọn ọgọ́sàn-an ó lé méje (187) ló sì fara pa níbi tíná ti ń jó. Iná yìí ni wọ́n gbà pé ó tíì ṣọṣẹ́ jù lórílẹ̀-èdè náà láti ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Ìròyìn tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Gíríìsì ni pé ìkankan nínú àwọn arákùnrin wa ò fara pa, ìkankan nínú wọn ò sì kú. Àmọ́ ó gba pé kí gbogbo àwọn ará wa tó wà níbi tí àjálù náà ti wáyé kó kúrò lágbègbè náà, àwọn ará tó sì wà láwọn ìjọ itòsí sì ti gbà wọ́n sílé. Yàtọ̀ síyẹn, ilé mẹ́rin tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló bà jẹ́ gan-an, ilé kan tiẹ̀ wà tó bà jẹ́ kọjá àtúnṣe.

A ò dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa tí àjálù yìí ṣẹlẹ̀ sí àtàwọn ará wa tí ìfẹ́ ará mú kí wọ́n gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwọn sílé. (Jòhánù 13:​34, 35) A mọ̀ pé Jèhófà á túbọ̀ máa gbé àwọn ará wa ró lásìkò wàhálà yìí.