DECEMBER 23, 2019
GUATEMALA
Àwọn Ọlọ́pàá Àtàwọn Panápaná Jàǹfààní Látinú Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Tó Dá Lórí Bíbélì
Ní May 2019, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Guatemala fọwọ́ sí i pé ká kọ́ àwọn ọlọ́pàá àti àwọn panápaná orílẹ̀-èdè náà láwọn ìlànà Bíbélì tó máa wúlò fún wọn lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Ní báyìí, àwọn panápaná àtàwọn ọlọ́pàá tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (450) ló ti lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí láwọn ìlú wọ̀nyí: Coatepeque, Colomba Costa Cuca, Malacatán àti San Rafael Petzal.
Alàgbà ni Juan Carlos Rodas, ó sì wà lára àwọn tó ń bójú tó ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó ṣàlàyé pé: “Ó ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) báyìí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lọ ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ẹ̀kọ́ Bíbélì láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀ èdè Guatemala. Àwọn aláṣẹ tó ń bójú tó àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí ṣàkíyèsí pé ìwà àwọn ẹlẹ́wọ̀n tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń sunwọ̀n sí i. Ìyẹn ló mú kí wọ́n dábàá pé ká wá kọ́ àwọn ọlọ́pàá àtàwọn panápaná nírú ẹ̀kọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀.”
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America ló ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, wọ́n sì ṣètò pé kó máa wáyé lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, ìdálẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sì máa ń tó nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15). Ara àwọn ohun tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ níbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ni bí wọ́n ṣe lè bá àwọn èèyàn lò, bí wọ́n á ṣe lo ọlá àṣẹ wọn lọ́nà tó tọ àti bí wọ́n ṣe lè jọ máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan. Àwọn arákùnrin tó ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí fún wọn láwọn ìtẹ̀jáde tó bá ohun tí wọ́n sọ mú, wọ́n fi àwọn fídíò látorí ìkànnì wa hàn wọ́n, wọ́n sì tún kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè wá àwọn ìsọfúnni tó wúlò lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni láti dá àwọn ọlọ́pàá àtàwọn panápaná lẹ́kọ̀ọ́. A retí pé wọ́n á ma báa nìṣó láti jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó wúlò tó wà nínú Bíbélì.—2 Tímótì 3:16.