Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 5, 2018
GUATEMALA

Òkè Ayọnáyèéfín Bú Gbàù ní Guatemala

Òkè Ayọnáyèéfín Bú Gbàù ní Guatemala

Ní Sunday, June 3, 2018, òkè ayọnáyèéfín tí wọ́n ń pè ní Volcan de Fuego bú gbàù ní orílẹ̀-èdè Guatemala. Eérú gbígbóná tú jáde, èéfín tó ń jáde níbẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó kìlómítà mẹ́sàn-án. Ó kéré tán, ìjọ mẹ́wàá ló wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé. Àmọ́ a dúpẹ́ pé ìkankan nínú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ò fara pa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn mẹ́jọ nínú wọn la ti ní kí wọ́n kúrò níbi tí wọ́n ń gbé torí àtidáàbò bò wọ́n. Ọ̀rọ̀ inú 2 Kọ́ríńtì 8:14 àti 15 ti mú kí àwọn àyíká tó wà nítòsí ṣèrànwọ́ láti pèsè oúnjẹ, ilé àti ohun ìrìnnà fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí.