JUNE 16, 2016
HAITI
Ìjọba Haiti fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àmì Ẹ̀yẹ Torí Bí Wọ́n Ṣe Ran Àwọn Aláàbọ̀ Ara Lọ́wọ́
ÌLÚ PORT-AU-PRINCE, lórílẹ̀-èdè Haiti—Ọ́fíìsì Akọ̀wé Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Aláàbọ̀ Ara ní Haiti (ìyẹn Ìgbìmọ̀ BSEIPH) fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Haiti ní àmì ẹ̀yẹ. Àwọn tó ti ṣèrànwọ́ fáwọn aláàbọ̀ ara ni ìgbìmọ̀ náà máa ń fún nírú àmì ẹ̀yẹ yìí. Níbi ayẹyẹ kan tí wọ́n ṣe, tí Olórí Ìjọba ìgbà yẹn tó ń jẹ́ Evans Paul wà níbẹ̀, Daniel Lainé tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Haiti gba àmì ẹ̀yẹ ní apá “Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àti Ìmọ̀ Ẹ̀rọ,” bá a ṣe rí i nínú fọ́tò tó wà lókè yìí. December 3, 2015 ni wọ́n ṣe ayẹyẹ náà, wọ́n fẹ́ kó bọ́ sí ọjọ́ táwọn èèyàn mọ̀ sí Ọjọ́ Àwọn Aláàbọ̀ Ara Kárí Ayé.
Guerline Dardignac tó jẹ́ olórí àwọn òṣìṣẹ́ Ìgbìmọ̀ BSEIPH sọ̀rọ̀ lórí ipa táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kó nínú ọ̀rọ̀ àwọn aláàbọ̀ ara. Ó ṣàlàyé pé “àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Haiti ń sapá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti má fọwọ́ rọ́ àwọn aláàbọ̀ ara sẹ́yìn láwùjọ. Wọ́n gba ti àwọn aláàbọ̀ ara rò ní ti pé wọ́n ṣètò bó ṣe máa rọrùn fún wọn, pàápàá àwọn tó nílò ìrànwọ́ àrà ọ̀tọ̀, láti ráyè wọnú àwọn ilé ìjọsìn wọn, ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún ń ṣèjọsìn àtàwọn ìgbòkègbodò míì lédè àwọn adití (ìyẹn Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà), wọ́n sì ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde lédè àwọn afọ́jú àtàwọn fídíò lédè àwọn adití. Gbogbo èyí ń jẹ́ kí àwọn aláàbọ̀ ara yìí lè lo ìmọ̀ ẹ̀rọ, kí wọ́n sì lè bá àwọn míì sọ̀rọ̀.”
Ẹ̀ẹ̀kejì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gba irú àmì ẹ̀yẹ yìí rèé látìgbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára gan-an ti wáyé ní Haiti, tó pa àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé méjìlélógún (222,000), tó sì ṣe àwọn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) léṣe. Èyí tún jẹ́ kí iye àwọn tó jẹ́ aláàbọ̀ ara pọ̀ sí i. Ọdún 2013 làwọn Ẹlẹ́rìí gba àmì ẹ̀yẹ wọn àkọ́kọ́; lọ́dún yẹn, Ìgbìmọ̀ BSEIPH sọ pé àwọn mọrírì báwọn Ẹlẹ́rìí ṣe sapá láti ṣètò tó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn aláàbọ̀ ara láti ráyè wọnú ibi ìjọsìn wọn tó wà nílùú Cayes, ní Haiti.
Ọ̀gbẹ́ni Lainé sọ pé: “A mọrírì àwọn àmì ẹ̀yẹ yìí torí pé àwọn aláṣẹ kíyè sí bá a ṣe ń sapá láti ran àwọn tó jẹ́ aláàbọ̀ ara lọ́wọ́, inú wa sì dùn láti ṣe àwọn nǹkan yìí, ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe ló jẹ́.”
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000
Haiti: Daniel Lainé, 509-2813-1560