Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 15, 2018
HAITI

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Àríwá Ilẹ̀ Haiti

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Àríwá Ilẹ̀ Haiti

Ní Saturday, October 6, 2018, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára wáyé ní agbègbè àríwá ilẹ̀ Haiti, ó pa èèyàn mẹ́tàdínlógún (17), ó sì ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tó fara pa.

Ìròyìn tá a gbọ́ fi hàn pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú; àmọ́ àwọn méjì ṣèṣe. Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ látọ̀dọ̀ àwọn alábòójútó àyíká fi hàn pé ilé mẹ́rìnlélógójì (44) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rin ló bà jẹ́. Ní ìlú Port-de-Paix, nǹkan bí àádọ́ta (50) àwọn ará àti ìdílé wọn ló ní láti kúrò níbi tí wọ́n ń gbé torí àwọn ilé náà lè wó nígbàkigbà. Àwọn ará inú ìjọ tó wà lágbègbè náà ló ń tójú àwọn ìdílé yìí. Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka nílẹ̀ Haiti pẹ̀lú arákùnrin méjì tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ lọ sáwọn ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè mọ bó ṣe tó, kí wọ́n sì fún àwọn ara níṣìírí. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbẹ̀ láti pèsè àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì.

Ọkàn wa wà lọ́dọ̀ àwọn ará wa ní Haiti, a sì ń gbàdúrà fún wọn. A dúpẹ́ pé Baba wa ọ̀run ti ṣèlérí pé ìfẹ́ òun tí kìí yẹ̀ máa tu àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ òun nínú.—Sáàmù 119:76.