AUGUST 31, 2017
HONG KONG
Ìjì Líle Hato Jà Nílùú Hong Kong àti Macau
Ní Wednesday, August 23, ìjì líle tó léńkekà kan tó ń jẹ́ Hato, jà ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Ṣáínà, ó sì dé ìlu Hong Kong àti Macau. Kò sí ẹni kankan tá a gbọ́ pé ó kú nílùú Hong Kong, àmọ́ àwọn mẹ́tàlélógbọ̀n [34] ló fara pa. Nílùú Macau, ó kéré tán àwọn mẹ́sàn-án ló kú, àwọn mẹ́tàléláàdọ́jọ [153] sì fara pa.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìi Jèhófa ní ìlu Hong Kong, tó tún ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí nílùú Macau, ròyìn pé kò sí Ẹlẹ́rìi kankan tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ni kò ní iná àti omi tí wọ́n máa lò nílùú Macau. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ń ṣètò pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí lágbègbè yẹn láti pèsè omi àti àwọn ohun míì tí àwọn ará wọn tí àjálù yìí dé bá nílò.
Àwọn Ẹlẹ́rìi Jèhófa tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn márùn-ún [5,500] ló ń gbé nílùú Hong Kong, àwọn ọgọ́rùn-un mẹ́ta àti ógún [320] ló sì ń gbé nílùú Macau.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
Hong Kong: Danny Steensen, +852-3950-3500