Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Royal Courts of Justice rèé, ibẹ̀ ni Ilé Ẹjọ́ Gíga àti Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Orílẹ̀-Èdè England àti Wales wà

MAY 12, 2020
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

Ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè England fòǹtẹ̀ lu ẹ̀tọ́ wa láti pinnu ẹni tó máa jẹ́ ọ̀kan lára wa

Ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè England fòǹtẹ̀ lu ẹ̀tọ́ wa láti pinnu ẹni tó máa jẹ́ ọ̀kan lára wa

Ní March 17, 2020, Ilé-Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Orílẹ̀-Èdè England àti Wales fọwọ́ òsì da ìpẹ̀jọ́ tí wọ́n pè lòdì sí ìpinnu ìdájọ́ Ilé-Ẹjọ́ Gíga jù lọ nù. Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn wá fi òǹtẹ̀ lù ú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti yọ ẹnikẹ́ni lẹ́gbẹ́ níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Bíbélì.

Nínú ìdájọ́ tí wọ́n gbé kalẹ̀, ilé-ẹjọ́ yìí pinnu pé ìjọ kan ní ẹ̀tọ́ láti ṣèfilọ̀ pé ẹnìkan kìí ṣe ara àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àti pé irú ìfilọ̀ bẹ́ẹ̀ kìí ṣe láti ba ẹni bẹ́ẹ̀ lórúkọ jẹ́. Adájọ́, Richard Spearman, Q.C., sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀ pé: “Kò ṣàjèjì pé àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn tí Bíbélì bá jẹ́ atọ́nà wọn, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, máa ní agbára láti yọ ẹlẹ́ṣẹ̀. Láìsí àníàní, ó ṣe pàtàkì nítorí pé ẹni tí kò bá tẹ̀lé tàbí tí kò wù láti tẹ̀lé ìtọ́ni Bíbélì kìí ṣe apákan ìjọsìn bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe pàtàkì láti yọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n máa kó èèràn ran àwọn míì tó ní ìgbàgbọ́.”

Àwọn olùpẹ̀jọ́ béèrè pé kí Ilé-Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbà wọ́n láàyè láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí Ilé-Ẹjọ́ Gíga jùlọ dá. Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn kọ̀, wọ́n ní ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí wọ́n fẹ́ pè “kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀,” àti pé ẹjọ́ tí ilé-ẹjọ́ tó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tẹ́lẹ̀ dá “lọ bó ṣe yẹ” àti pé “agbára láti yọ ẹnìkan lẹ́gbẹ́ yẹ láwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn.”

Nígbà tí Shane Brady, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ìdájọ́ yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, bíi ti ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, ti ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Kánádà, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù àti ti Amẹ́ríkà. Gbogbo ìdájọ́ wọ̀nyí fìdí ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti pinnu ẹni tó máa jẹ́ ọ̀kan lára wọn múlẹ̀.”

Inú wá dùn láti rí i pé ilé ẹjọ́ fòǹtẹ̀ lu ẹ̀tọ́ wa láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, ká sì dáàbò bo ìjọ wa lọ́wọ́ ewu​—1 Kọ́ríńtì 5:11; 2 Jòhánù 9-11.