Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 5, 2017
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Britain Gba Àmì Ẹ̀yẹ Tó Ga Jù Lọ Látọ̀dọ̀ Àjọ BREEAMn

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Britain Gba Àmì Ẹ̀yẹ Tó Ga Jù Lọ Látọ̀dọ̀ Àjọ BREEAMn

LONDON—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun nílùú Britain, àjọ BREEAM (Building Research Establishment Environmental Assessment Method) sì ti fún wa ní àmì ẹ̀yẹ tó gà jù lọ. Àjọ yìí ló gbawájú jù lọ lára àwọn tó ń fi ìlànà ilé kíkọ́ ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ ìkọ́lé, wọ́n sì máa ń fún àwọn èèyàn ní àmì ẹ̀yẹ níbàámu pẹ̀lú bí wọ́n bá ṣe tẹ̀ lé ìlànà ìkọ́lé tó. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí wà ní máìlì mẹ́tàlélógójì [43] sí ìlà oòrùn ìlú London, ní àgbègbè Chelmsford, Essex, òun sì ni ilé kejì tí àjọ BREEAM fún ní àmì ẹ̀yẹ tó ga jù lọ.

Ní May 25, 2017, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àgbègbè Chelmsford ni ilé kejì tí àjọ BREEAM fún ní àmì ẹ̀yẹ tó ga jù lọ.

Àjọ BRE (Building Research Establishment) ló dá àjọ BREEAM sílẹ̀, láti máa fi ìlànà ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ ìkọ́lé, kí wọ́n lè mọ bó ṣe pegedé tó. Lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń wò ni: bí wọ́n ṣe ṣọ́ iná mànàmáná lò tó, bí ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ ọ kò ṣe ní kó bá ìléra àwọn èèyàn tá á sì mú kára tuni, bí wọ́n ṣe dárà sí ilé náà tó, bí wọ́n ṣe fọgbọ́n lo ilẹ̀, bí wọ́n ṣe ṣọ́ nǹkan lò tó, bí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣe wà létòlétò, bí wọ́n ṣe sapá tó láti má ṣe ba àyíká jẹ́, bí wọ́n ṣe ń kó nǹkan láti ibì kan sí ibòmíì, bí wọ́n ṣe bójú tó ìdọ̀tí àti bí wọ́n ṣe lo omi. Àwọn àmì ẹ̀yẹ tí èèyàn lè gbà ni: O Gbìyànjú, O Ṣe Dáadáa, O Ṣe Dáadáa Gan-an, O Ta Yọ tàbí O Ta Yọ Jù Lọ. Ohun tí ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àgbègbè Chelmsford pinnu ni pé kí wọ́n tó lè gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ẹ̀ká ọ́fíìsì wọn sí àgbègbè yẹn, ó kéré tán, wọ́n gbọ́dọ̀ dójú ìlà O Ṣe Dáadáa Gan-an lórí òṣùwọ̀n àjọ BREEAM. Ọ̀gbẹ́ni Neil Jordan, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà lára ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àgbègbè Chelmsford sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lé ìlànà tá a gbé kalẹ̀ lórí ilé tí wọ́n fẹ́ kọ́, kódà wọ́n tún fakọyọ kọjá ìlànà tí ìgbìmọ̀ náà gbé kalẹ̀.” Ó tún sọ pé “àmúyangàn ni ilé yìí jẹ́ fún ìlú wa, torí pé wọ́n kọ́ ọ lọ́nà tó pegedé jù lọ tí kò sì ṣàkóbá fún ìlera àti àyíká wa.”

Láfikún sí àmì O Ta Yọ Jù Lọ tá a gbà yìí, wọ́n tún gbóṣùbà fún wa pé ọ̀nà tá a gbà kọ́ ilé náà kò ṣàkóbá kankan fún àyíká. Ìdí sì ni pé a ṣètò ibì kan táwọn òṣìṣẹ́ wa á máa gbé nítòsí ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà, èyí máa dín lílọ̀ bíbọ̀ mọ́tò kù, a tún lo àwọn bọ́ọ̀sì kéékèèké àtàwọn ọkọ̀ míì tí kì í yọ èéfín púpọ̀ láti fi máa gbé àwọn òṣìṣẹ́ lọ bọ̀, ìsapá yìí jẹ́ ká ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé wa lọ́nà tí èéfín ò fi ní pọ̀. Èyí ló mú ká gba àmì ẹ̀ye BREEAM fún iṣẹ́ ìkọ́lé “tó pegedé.” Àwa sì kọ́kọ́ gba àmì ẹ̀yẹ yìí. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Jordan so pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé yìí lọ́nà tó dín èéfín olóró kù gan-an, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gba máàkì láwọn apá kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”

Pallab Chatterjee, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ àjọ BREEAM tó ń ṣàyẹ̀wò ilé kíkọ́.

Ọ̀gbẹ́ni Pallab Chatterjee tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ àjọ BREEAM tó ń ṣàyẹ̀wò ilé kíkọ́ sọ ohun tó rí nígbà tó bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ àti bá a ṣe ń ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó sọ pé: “Ó wú mi lórí láti rí bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́ tí wọ́n sì bá ara wọn ṣiṣẹ́ bí ọ̀rẹ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé náà, èyí ṣọ̀wọ́n gan-an. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sapá gan-an láti ṣe ọ̀pọ̀ lára ohun tí àjọ BREEAM ń wò nínú iṣẹ́ ìkọ́lé. Kì í ṣe torí pé wọ́n fẹ́ gba àmì ẹ̀yẹ ni wọ́n ṣe ń ṣe ohun tí wọ́n ṣe, síbẹ̀ gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti kọ́ ilé náà lọ́nà tó pegedé ti pa kún iyì àjọ BREEAM. Ohun tó wú mi lórí jù ni bí wọ́n ṣe fi ire àwọn aládùúgbò wọn sọ́kàn nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà tí wọ́n sì tún ronú nípa àwọn tí wọ́n á máa bá gbé ládùúgbò yẹn lọ́jọ́ iwájú; ìyẹn hàn nínú bí wọ́n ṣe kọ́lé wọn. Ọ̀kan lára iṣẹ́ ìkọ́lé tí mo gbádùn jù ni iṣẹ́ wọn yìí.”

Andrew Schofield tó jẹ agbọ̀rọ̀sọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Britain sọ pé: “Láti nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti wà ní London. Àmọ́ ó ti wá pọn dandan pé ká mú un gbòòrò sí i torí pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i nílò Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ilẹ̀ tá a fẹ́ kọ́ ọ́fíìsì yìí sí fẹ̀ tó éèkà márùnlélọ́gọ́rin [85]. A ti bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ ibẹ̀ mọ́ láti April 2015, a retí pé iṣẹ́ ìkólé náà á parí tó bá máa fi di ìparí ọdún 2019.”

Agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

United Kingdom: Andrew Schofield, +44-20-8906-2211