AUGUST 16, 2019
ÍŃDÍÀ
Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Òjò Mú Kí Omi Ya Wọ Ìwọ̀ Oòrùn Íńdíà
Bí ìròyìn kan ṣe sọ, ó kéré tán, ọgọ́rùn-ún kan àti mọ́kàndínláàádọ́rin (169) èèyàn ló bá àkúnya omi tó ṣẹlẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Íńdíà lọ. Àwọn ìpínlẹ̀ tọ́rọ̀ kàn ni ìpínlẹ̀ Gujarat, Maharashtra, Karnataka àti Kerala.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Íńdíà fi yé wa pé kò sí ìkankan nínú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó bá àkúnya omi náà lọ tàbí tó fara pa. Àlàyé tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe rèé:
Ìpínlẹ̀ Gujarat: Ní ìlú Vadodara, àwọn akéde márùnlélógóje (ni àkúnya omi náà ba ilé wọn jẹ́. Àmọ́, mìmì kan ò mi ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Gujarati tó wà ní ìlú Vadodara.
Ìpínlẹ̀ Maharashtra: Ní ìlú Mumbai, ìdílé mẹ́fà ni àkúnya omi náà ba ilé wọn jẹ́. Ní ìlú Sangli, tó wà ní nǹkan bíi 378 kìlómítà sí ìlú Mumbai, àwọn akéde mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sá fi ilé wọn sílẹ̀. Àwọn ará ní ìlú kan tó wà nítòsí gbà wọ́n sílé.
Ìpínlẹ̀ Karnataka: Ìdílé mẹ́fà ni àkúnya omi náà ti mú kí wọ́n sá fi ilé wọn sílẹ̀. Ìpínlẹ̀ yìí ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wà, àmọ́ àkúnya omi yìí ò ṣe jàǹbá èyíkéyìí fún ẹ̀ka ọ́fíìsì náà.
Ìpínlẹ̀ Kerala: Nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún kan (100) ìdílé ló ti ṣí lọ sáwọn ibi tó ga, wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ará wa tó wà níbẹ̀. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ń darí ètò ìrànwọ́ láwọn ibi tọ́rọ̀ kàn. Àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn aṣojú Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó Sì Ń Kọ́ Ọ náà sì ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun lórí ọ̀rọ̀ yìí kí wọ́n lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tọ́rọ̀ kàn lọ́wọ́. Wọ́n fún wọn láwọn ohun kòṣeémáàní bíi omi tó ṣé e mu, wọ́n ń fún wọn níṣìírí, wọ́n sì ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà má ṣe fi àwọn ará wa yìí sílẹ̀. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tó jẹ́ pé “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà” ló máa wà níbi gbogbo dípò àjálù.—Sáàmù 37:11.