Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 31, 2019
ÍŃDÍÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Jáde ní Èdè Telugu ní Orílẹ̀-Èdè Íńdíà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Jáde ní Èdè Telugu ní Orílẹ̀-Èdè Íńdíà

Ní October 25, 2019, Arákùnrin Ashok Patel tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Íńdíà mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Telugu ní àpéjọ agbègbè tá a ṣe ní International Convention Centre tó wà nílùú Hyderabad, lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

Àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mọ́kànléláàádọ́rùn-ún (91,900, 000) ló ń sọ èdè Telugu, ìyẹn ló mú kó jẹ́ èdè kẹta tí àwọn èèyàn ń sọ jù ní Íńdíà lẹ́yìn èdè Hindi àti Bengali. Ní báyìí, àwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ló ń sìn láwọn agbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Telugu, àmọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti méjìdínláàádọ́rin (8,868) làwọn tó wá sí àpéjọ náà. Èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló wà ní agbègbè yẹn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, kódà àyíká méjì la ti dá sílẹ̀ lọ́dún yìí.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè tó wà lára àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Telugu náà fún odindi ọdún márùn-ún kíyè sí i pé kì í rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti lóye àwọn èdè àtijọ́ tí wọ́n lò nínú àwọn Bíbélì Telugu míì. Ó wá sọ pé: “Pẹ̀lú ìtumọ̀ tuntun yìí, Jèhófà máa bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ ní tààràtà lọ́nà tó máa yé wọn dáadáa tí kò sì ní lọ́jú pọ̀.” Atúmọ̀ èdè míì tún fi kún un pé: “Lóde ẹ̀rí, àwọn èèyàn á máa tètè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá kà fún wọn torí pé ó rọrùn.”

Láfikún síyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn Bíbélì tó wà lédè Telugu ló ti yọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà kúrò nínú Bíbélì wọn, torí náà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti mọ orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè. Ó tún máa jẹ́ kí wọ́n mọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bí ọkàn àti ẹ̀mí. Ìdí sì ni pé ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Hindu làwọn tó tú àwọn Bíbélì míì gbé ìtumọ̀ wọn kà.

Akéde kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé Bíbélì Telugu yìí máa ran àwọn tó bá kà á lọ́wọ́ láti túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an!” Ó ṣe kedere pé Bíbélì tuntun tá a mú jáde lédè Telugu yìí máa ran àwọn tó bá kà á lọ́wọ́ láti ‘tọ́ Jèhófà wò, kí wọ́n sì rí i pé ẹni rere ni.’—Sáàmù 34:8.