JUNE 18, 2020
ÍŃDÍÀ
Àwọn Atúmọ̀ Èdè ní Orílẹ̀-èdè India Ń Báṣẹ́ Lọ Láìka Ti Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Gbòde Kan Sí
Àrùn COVID-19 tó gbòde kan yìí kò fẹ́ mú nǹkan rọrùn fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè (RTO) mọ́kànlá, níbi tí wọ́n ti ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè mẹ́rìndínlógójì (36). Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn atúmọ̀ èdè yìí ń rí ojútùú sáwọn ìṣòro tó ń yọjú yẹn, wọ́n sì ń báṣẹ́ wọn nìṣó.
Iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè kì í ṣe iṣẹ́ tí ẹnì kan lè dá ṣe. Àmọ́ bí àrùn COVID-19 ṣe túbọ̀ ń tàn kálẹ̀, ìjọba orílẹ̀-èdè India ṣe òfin kónílégbélé, wọ́n ò sì fọ̀rọ̀ náà ṣeré rárá, èyí ló wá mú kó ṣòro fún àwọn atúmọ̀ èdè yẹn láti wà papọ̀ níbi kan náà. Bákàn náà, àwọn amojú ẹ̀rọ tó máa ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn fídíò wa, tí wọ́n sì máa ń gba ohùn àwọn èèyàn sílẹ̀ kò lè ṣiṣẹ́ wọn nínú ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.
Àtorí ẹ̀rọ ayélujára làwọn atúmọ̀ èdè yẹn ti máa ń bára wọn ṣiṣẹ́ báyìí dípò kí wọ́n jọ wà níbì kan náà, kódà tí wọ́n bá fẹ́ gba ohùn àwọn èèyàn sílẹ̀, ọ̀tọ̀ nibi tí ẹni tó ń mojú ẹ̀rọ àtẹni tó ń kàwé máa wà. Èyí ló wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ará tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè míì bíi Bangladesh àti Amẹ́ríkà láti ràn àwọn atúmọ̀ èdè tó wà ní India lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Àwọn ará yẹn tún ti wá rí àwọn ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà ṣe àwọn fídíò tó wà fún àwọn adití, láì jẹ́ pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà sún mọ́ra wọn. Àwọn atúmọ̀ èdè kan tiẹ̀ ti sọ yàrá wọn di ibiṣẹ́ wọn, kódà wọ́n ti fi àwọn páálí àtàwọn nǹkan míì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí iṣẹ́ wọn jáde dáadáa, àwọn kan tiẹ̀ ń fi fóònù wọn ṣe fídíò dípò àwọn kámẹ́rà tó le ńlẹ̀.
Àmọ́ yàtọ̀ sóhun táwọn atúmọ̀ èdè yẹn ṣe, ṣe ni wọ́n gbára lé Jèhófà pé ó máa ran àwọn lọ́wọ́ láti má ṣe rẹ̀wẹ̀sì, ó sì máa fún wọn lókun láti máa báṣẹ́ náà lọ. Ẹ gbọ́ ohun táwọn kan lára wọn sọ:
Arákùnrin Jose Francis láti ìlú Kolkata sọ pé, “Tí ìṣòro kan bá yọjú, àwa èèyàn máa ń ríi bí ògiri, àmọ́ Jèhófà mọ ọ̀nà àbáyọ.”
Arábìnrin Bindu Rani Chandan láti ìlú Bangalore sọ pé, “Ohun tó ń fún mi láyò lásìkò tí nǹkan nira yìí ni pé Jèhófà ń lò mí, ó sì jẹ́ kí n wúlò fún òun.”
Arábìnrin Rubina Patel láti ìlú Vadodara sọ pé, “Kò sí ohun tó lè dá Jèhófà àti ètò rẹ̀ dúró, kódà àrùn corona gan-an ò tó bẹ́ẹ̀.”
Orí wa máa ń wú tá a bá rántí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa. Ó dá wa lójú pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló ń jẹ́ kí wọ́n ṣe gbogbo àṣeyọrí tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó sì máa jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nímùúṣẹ, èyí tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”—Mátíù 24:14.