Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 30, 2020
ÍŃDÍÀ

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Mẹ́ta ní Íńdíà

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Mẹ́ta ní Íńdíà

Ní Sunday, October 25, 2020, a mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè mẹ́tà ní Íńdíà, ìyẹn Gujarati, Kannada àti Punjabi. Wọ́n mú Bíbélì yìí jáde látorí ẹ̀rọ nínú àsọyé tá a ti gbà sílẹ̀. Àtilé làwọn ará ti wo fídíò náà. Wọ́n sì láǹfààní láti wa Bíbélì yìí sórí ẹ̀rọ wọn, kété lẹ́yìn tí wọ́n wò ó tán.

Gujarati

Àwọn èèyàn tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gọ́ta (61) ló ń sọ èdè Gujarati kárí ayé.

Àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́fà tí wọ́n pín sí àwùjọ méjì ló túmọ̀ Bíbélì yìí, ó sì gbà wọ́n lọ́dún méje láti parí ẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè yẹn sọ pé: “Inú wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n mú Bíbélì yìí jáde. Ìtúmọ̀ Bíbélì náà rọrùn, kódà àwọn ọmọdé máa lóye ẹ̀.”

Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Gbogbo ibi tí orúkọ Jèhófà wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ló ti fara hàn nínú Bíbélì yìí. A mọ̀ pé ó máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ wọn, á sì mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára.”

Bíbélì yìí rọrùn lóye, torí náà ó dá wa lójú pé ó máa ṣe àwọn ará wa láǹfààní gan-an, á sì ran “àwọn oníwà pẹ̀lẹ́” lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ọ̀nà Jèhófà.​—Sáàmù 25:9.

Kannada

Bí wọ́n ṣe ń sọ èdè Kannada yàtọ̀ gan-an sí bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́. Bí wọ́n sì ṣe ń sọ ọ́ níbì kan yàtọ̀ sí ti ibòmíì. Torí náà, kò rọrùn fáwọn atúmọ̀ èdè láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tó péye, tí ò ní bomi la ohun tó wà nínú Bíbélì, tá sì yé gbogbo àwọn tó ń sọ èdè yìí ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ ọ́.

Ó gba àwọn atúmọ̀ èdè ní ohun tó lé ní ọdún méje kí wọ́n tó parí ìtúmọ̀ Bíbélì yìí. Àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́wàá ló sì ṣiṣẹ́ lé e lórí. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ọdún 2021 ni mo rò pé a máa lè mú Bíbélì yìí jáde torí àrùn Corona tó ń jà. Àmọ́ bá a ṣe mú un jáde ṣáájú ìgbà yẹn jẹ́ kí n rí i pé kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró.”

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè yẹn tún sọ pé: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n mú Bíbélì yìí jáde, torí ó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń sọ èdè Kannada láti ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lédè ìbílẹ̀ wọn, wọ́n sì tún máa rí orúkọ Ọlọ́run ní gbogbo ibi tó yẹ kó wà!”

Ó dá wa lójú pé Bíbélì yìí máa wúlò gan-an fáwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (2,800) tí wọ́n ń sọ èdè Kannada ní ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Íńdíà ń bójú tó. Bíbélì yìí á tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) èèyàn tó ń sọ èdè yìí kárí ayé, kí wọ́n lè mọ ‘ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run tó jinlẹ̀.’​—Róòmù 11:33.

Punjabi

Àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́fà ló ṣiṣẹ́ lórí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Punjabi, ọdún méjìlá ló sì gbà wọ́n láti parí ẹ̀. Bíbélì yìí máa wúlò gan-an fáwọn tó ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù tó ń sọ èdè Punjabi ní orílẹ̀-èdè Íńdíà àti láwọn ibòmíì kárí ayé.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè yẹn sọ pé: “A ò fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn nǹkan tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ yìí. Àmọ́ Jèhófà tì wá lẹ́yìn láti parí ẹ̀. Bíbélì yìí máa fún ìgbàgbọ́ àwọn ará wa lókun, ó máa fọkàn wọn balẹ̀, á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti fara da àwọn ìṣòro tí wọ́n máa kojú.”

Atúmọ̀ èdè míì sọ pé: “Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ máa gbádùn Bíbélì yìí gan-an, pàápàá àwọn apá tó ní ewì. Wọ́n tún máa jàǹfààní àwọn àfikún àlàyé tó wà nínú ẹ̀.”

Àwa náà bá àwọn ará wa yìí yọ̀, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn “iṣẹ́ àgbàyanu” rẹ̀, torí ‘wọ́n pọ̀ ju ohun tá a lè ròyìn.’​—Sáàmù 40:5.