Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 17, 2018
ÍŃDÍÀ

Ẹ̀mí Ṣòfò Nígbà Tí Òkè Ya Lulẹ̀ Lápá Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Íńdíà

Ẹ̀mí Ṣòfò Nígbà Tí Òkè Ya Lulẹ̀ Lápá Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Íńdíà

Ìjì líle tó máa ń bá òjò rìn jà ní ìpínlẹ̀ Kerala, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ó sì mú kí òkè ya lulẹ̀ níbi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gbẹ̀mí ó kéré tán, èèyàn márùndínlọ́gọ́rin (75). Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ojú Ọjọ́ Nílẹ̀ Íńdíà (India Meteorological Department) sọ pé ìjì líle tó máa ń jà lápá gúúsù ìwọ̀ oòrùn ayé ló tíì rọ òjò tó rinlẹ̀ jù lọ lápá ibí yìí nínú ìtàn.

Ó dùn wá gan-an nígbà tá a gbọ́ ìròyìn láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Íńdíà pé nígbà àjálù yìí, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n ti lé ní lẹ́ni ọgọ́ta (60) ọdún àti akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan pàdánù ẹ̀mí wọn, bákan náà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì ṣèṣe gan-an, wọ́n sì ti ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn. Yàtọ̀ síyẹn, arákùnrin wa kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) bómi lọ níbi tó ti fẹ́ ran ará àdúgbò rẹ̀ lọ́wọ́.

A dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù (DRC) sílẹ̀ kí wọ́n lè wo ibi tí nǹkan bà jẹ́ dé, kí wọ́n sì ṣètò ìrànwọ́. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ni wọ́n lò láti ṣe iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí. Ìròyìn tá a sì kọ́kọ́ gbọ́ fi hàn pé ó kéré tán, mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) lára ilé àwọn ará wa ló wó tàbí tó bà jẹ́. Nǹkan bí ìdílé márùnlélọ́gọ́rin (85) ìyẹn (akéde 475) ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú kí wọ́n kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, tí wọ́n sì lọ ń gbé nílé àwọn ará tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. A gbọ́ pé omi ọ̀gbàrá ti mu àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan débì kan. Ìgbìmọ̀ DRC ṣì wà ní sẹpẹ́ torí ìròyìn tá a gbọ́ ni pé òjò tó rinlẹ̀ ṣì máa tún rọ̀ láìpẹ́.

Àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àti alábòójútó àyíká kan lágbègbè náà pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kí wọ́n lè tù wọ́n nínú, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí.

Ọkàn wa wà lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kàn, a sì ń gbàdúrà fún wọn. À ń retí ìgbà tí gbogbo irú àjálù yìí àti gbogbo ìrora tó máa ń bá a rìn á dohun ìgbàgbé.​—Ìṣípayá 21:​3, 4.