Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 28, 2018
ÍŃDÍÀ

Ìjì Líle Jà ní Íńdíà

Ìjì Líle Jà ní Íńdíà

Ní November 16, 2018, ìjì tí wọ́n pè ní Gaja ṣọṣẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ Tamil Nadu lórílẹ̀-èdè Íńdíà. Ó kéré tán, èèyàn mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) ló kú, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé àádọ́ta (250,000) ló sá fi ilé wọn sílẹ̀, ilé tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́rùn-ún (85,000) ló bà jẹ́ díẹ̀ tàbí tó bà jẹ́ pátápátá.

Ilé ọ̀kan lára àwọn ará wa nílùú Mannargudi, ní Tamil Nadu rèé. Igi wó lu ilé náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Íńdíà jábọ̀ pé ìjì náà ò pa ìkankan nínú àwọn ará wa, kò sì ṣe wọ́n léṣe. Àmọ́, ilé àwọn ará wa méjìdínlógójì (38) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì ló bà jẹ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù kí wọ́n ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn akéde tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n pín oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì.

Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa tí Ìjì Gaja ṣèpalára fún ní Íńdíà rí ìtùnú gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́.—1 Pétérù 5:2.