DECEMBER 4, 2020
INDONESIA
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde ní Èdè Ìbílẹ̀ Mẹ́rin Lórílẹ̀-èdè Indonesia
Ní November 28, 2020, a mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lórí ìwé àti lórí ẹ̀rọ ní èdè ìbílẹ̀ mẹ́rin tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Indonesia, ìyẹn èdè Batak Karo, Batak Toba, Javanese àti Nias. Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló mú Bíbélì yìí jáde nínú àsọyé tá a ti gbà sílẹ̀, a sì ṣàtagbà fídíò náà sáwọn ará tó wà lérékùṣù Indonesia. Àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì, ọgọ́rùn-ún méjì àti márùndínláàádọ́rin (41,265) ló wo ètò yìí. Nínú àsọyé náà, Arákùnrin Jackson tún sọ pé láìpẹ́ a máa mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Sunda lórí ẹ̀rọ.
Iṣẹ́ àṣekára táwọn atúmọ̀ èdè ṣe fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta àtààbọ̀ ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mú Bíbélì yìí jáde. Ó kéré tán, ó ju ọgọ́rùn-ún kan mílíọ̀nù èèyàn tó ń sọ ọ̀kan lára èdè ìbílẹ̀ mẹ́rin tá a ti mú Bíbélì tuntun náà jáde. Bákan náà, àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2,600) ló ń fi àwọn èdè yẹn ṣèpàdé, tí wọ́n sì ń lò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Torí pé ọ̀nà ìkọ̀wé tí kò bóde mu àti èdè àtijọ́ ló wọ́pọ̀ nínú ìtúmọ̀ Bíbélì ti tẹ́lẹ̀, kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti lóye ẹ̀. Atúmọ̀ èdè kan sọ pé: “Ní báyìí tá a ti ní odindi Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè tó bóde mu, ó ti túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn gbọ́ Ọ̀rọ̀ òun ní èdè tó rọrùn lóye, tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn.”
Arákùnrin Daniel Purnomo, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Orílẹ̀-èdè Indonesia sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn lásìkò tá a wà yìí, ní pàtàkì torí àrùn Corona. Torí náà, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń sọ èdè tá a tú Bíbélì yìí sí mọyì ẹ̀bùn náà gan-an, torí ó bọ́ sákòókò.”
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti túbọ̀ máa rí ẹ̀bùn pàtàkì yìí. A gbà pé Bíbélì náà á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ yẹn láti túbọ̀ jàǹfààní látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jémíìsì 1:17.