Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ará wa tún ilé ìdílé Nenosaban ṣe nílùú Kupang, lórílẹ̀-èdè Indonesia

JUNE 24, 2021
INDONESIA

Ìránwọ́ Tí Ètò Ọlọ́run Ṣe Fáwọn Ará Wa Lórílẹ̀-Èdè Indonesia Mú Kí Ìfẹ́ Wọn Túbọ̀ Lágbára, Ó sì Jẹ́rìí Fáwọn Èèyàn

Ìránwọ́ Tí Ètò Ọlọ́run Ṣe Fáwọn Ará Wa Lórílẹ̀-Èdè Indonesia Mú Kí Ìfẹ́ Wọn Túbọ̀ Lágbára, Ó sì Jẹ́rìí Fáwọn Èèyàn

Ní April 4, 2021, ìjì kan tí wọ́n ń pè ní Seroja jà lórílẹ̀-èdè Indonesia, ó sì ba nǹkan jẹ́ gan-an. Ètò ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe láti tún ilé àwọn ará wa tó bà jẹ́ ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ wọn túbọ̀ lágbára, ó sì tún jẹ́ káwọn tó kíyè sí wa fìyìn fún Jèhófà.

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù bá Arábìnrin Ela Ludjipau, tó jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ tún ilé rẹ̀ tó bà jẹ́ ṣe. Arábìnrin Ela sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àtàwọn ọmọ mi là ń dá gbé, kò ṣe mí bíi pé mo dá wà torí ìgbà gbogbo làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi ń ràn mí lọ́wọ́.” Arábìnrin míì tó ńjẹ́ Yuliana Baunsele sọ pé: “Nígbà tí mo rí àwọn ará tí wọ́n ń bọ̀ wá ràn mí lọ́wọ́ láìpẹ́ lẹ́yìn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀, ó wá túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà bìkítà nípa mi gan-an.”

Arákùnrin Dicky Thome, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sọ pé: “Inú mi dùn, ayọ̀ mi kún bí mo ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà nínú àìní. Ó mórí wa wú gan-an bá a ṣe ń rí báwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe mọrírì ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà. Ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára bá a ṣe ń kíyè sí bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún ààbò àti ìrànlọ́wọ́.”

Kì í ṣe àwọn ará wa nìkan ló kíyè sí ìfẹ́ tó wà láàrín wa. Àdúgbò tí ìpínyà wà láàrín àwọn ẹ̀yà ni Arákùnrin Marsel Banunaek àti ìdílé rẹ̀ ń gbé. Àwọn aládùúgbò rẹ̀ ò fẹ́ràn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, Arákùnrin Banunaek sọ pé ìgbà táwọn aládùúgbò òun rí báwọn ará wa tó wá láti ẹ̀yà tó yàtọ̀ síra ṣe wá ran ìdílé òun lọ́wọ́, àwọn kan lára wọn wá sọ fún òun pé: “Ìwà ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ gan-an sí bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ yín fún wa.” Arákùnrin Banunaek sọ pé: “Ó ya àwọn aládùúgbò wa lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí bí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ṣe wà láàárín wa. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa náà rí báwọn ará wa ṣe ń ṣoore fúnra wọn. Ní báyìí, wọ́n ti wá ń bi wá níbèérè nípa ohun tá a gbà gbọ́. A dúpẹ́ púpọ̀ pé a láwọn ará tó nífẹ̀ẹ́ wa!”

Ìdílé Nenosaban rèé níwájú ilé wọn tí wọ́n tún ṣe

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ ìjọba ìlú náà tó ń jẹ́ Yosi Duli Ottu sọ pé “àpẹẹrẹ rere” ni Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù jẹ́, wọ́n wà létòlétò, wọ́n sì tẹ̀ lé gbogbo àwọn ìlànà ààbò lórí àrùn COVID-19. Nígbà tí Yosi ń bá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ohun tẹ́ ẹ ṣe fáwọn ọ̀rẹ́ yín wú mi lórí gan-an. Ẹ tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí àjálù yẹn ṣẹlẹ̀. Ètó tó dáa lẹ ṣe láti pèsè ìrànwọ́, o sì hàn gbangba pé ẹ kúnjú ìwọ̀n, gbogbo ohun tẹ́ ẹ máa lò lẹ sì ní.”

Àjálù lè ba àwọn nǹkan ìní jẹ́, àmọ́ kò lè ba ìfẹ́ tòótọ́ àti ìṣọ̀kan táwọn Kristẹni tòótọ́ ní jẹ́. Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí bí “àwọn iṣẹ́ rere” wa ṣe ń jẹ́ kí ìfẹ́ tòótọ́ tá a ní síra wa lágbára sí i, tó sì ń jẹ́ káwọn míì máa “fògo” fún Jèhófà!—Mátíù 5:16.