Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìdílé Tunbonat rèé àtàwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n lé kúrò nílé ìwé. Wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méje, mẹ́wàá àti méjìlá

OCTOBER 30, 2019
INDONESIA

Ilé Ẹjọ́ Kan Lórílẹ̀-èdè Indonesia Ṣèdájọ́ Pé Àwọn Ọmọléèwé Ní Òmìnira Láti Sin Ọlọ́run

Ilé Ẹjọ́ Kan Lórílẹ̀-èdè Indonesia Ṣèdájọ́ Pé Àwọn Ọmọléèwé Ní Òmìnira Láti Sin Ọlọ́run

Ní August 8, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbófinró ti ìlú Samarinda dá àwọn ọmọdé mẹ́ta láre. Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ lé àwọn ọmọ náà kúrò nílé ìwé torí pé wọ́n ò kí àsíá, wọn ò sì kọ orin orílẹ̀-èdè. Ilé ẹjọ́ sọ pé kò bófin mu bí wọ́n ṣe lé àwọn ọmọ náà kúrò nílé-ìwé, wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pa dà sílé ìwé. Ìpinnu yìí sọ ọ́ di ìlànà pé òfin orílẹ̀-èdè Indonesia fàyè gba àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìlànà ẹ̀sìn wọn, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ àwọn ọmọdé torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí ẹ̀sìn àwọn òbí wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fàyè gbà.

December  2018 ni wọ́n lé Yonatan ọmọ ọdún méje, Yosua ọmọ ọdún mẹ́wàá àti Maria Tunbonat, ọmọ ọdún méjìlá kúrò nílé ìwé. Àmọ́, Ilé Ẹjọ́ Agbófinró sọ pé bí àwọn ọmọ náà ò ṣe kí àsíá tí wọn ò sì kọ orin orílẹ̀-èdè kò rú Òfin orílẹ̀-èdè náà tàbí òfin èyíkéyìí; kò sì túmọ̀ sí pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún àṣà ìbílẹ̀ tàbí àmì orílẹ̀-èdè.

Inú wa dùn pé ilé ẹjọ́ ṣe ìdájọ́ tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún ohun tó bá Bíbélì mu táwọn ọmọ náà gbà gbọ́, ó sì yọ̀ǹda fún wọn láti máa kàwé wọn nìṣó. A nírètí pé ìdájọ́ yìí á mú nǹkan rọrùn fún ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù lórílẹ̀-èdè Indonesia tí wọ́n ń fúngun mọ́ pé káwọn náà kí àsíá kí wọ́n sì kọ orin orílẹ̀-èdè.