Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 28, 2019
INDONESIA

Omíyalé Ṣẹlẹ̀ ní Indonesia

Omíyalé Ṣẹlẹ̀ ní Indonesia

Òjò tó rọ̀ ní agbègbè Papua tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Indonesia ní March 16, 2019 kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Òjò yìí fa omíyalé, àwọn tó pa lé ní ọgọ́rùn-ún kan (100), ọ̀pọ̀ ilé ló sì gbá lọ.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Indonesia sọ pé omíyalé yìí náà dààmú ọ̀pọ̀ lára àwọn ará tó ń gbé ní ìlú Sentani lágbègbè Papua. Ó dùn wá pé arákùnrin wa kan kú nígbà tí omi gbé ilé rẹ̀ lọ. Omi náà sì tún ba ilé mẹ́ta míì tó jẹ́ ti àwọn ará wa jẹ́. Ó ju ogójì (40) akéde tó ní láti kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, ọ̀dọ̀ àwọn ará lèyí tó pọ̀ jù nínú wọ́n sì ń gbé báyìí. A ti dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀ láti pèsè ohun táwọn ará nílò. Àwọn aṣojú ẹ̀ka àti alábòójútó àyílá tó wà lágbègbè náà lọ sáwọn apá ibi tí àjálù náà ti ṣẹ̀lẹ̀ láti fún àwọn ará ní ìṣírí látinú Bíbélì. Wọ́n sì tún wo bí ìránlọ́wọ́ táwọn ará nílò ṣe máa pọ̀ tó.

À ń rántí gbogbo àwọn ará tí àjálù yìí ṣẹlẹ̀ sí nínú àdúrà wa. A retí pé láìpẹ́, Jèhófà máa “máa gbé ikú mì títí láé,” á sì “nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn.”—Àìsáyà 25:8.