Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 23, 2018
INDONESIA

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Erékùṣù Kan ní Indonéṣíà

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Erékùṣù Kan ní Indonéṣíà

Ní ìparí oṣù July àti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù August, ilẹ̀ mì tìtì léraléra ní erékùṣù Lombok lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, ó gbẹ̀mí ó kéré tán, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́rìndínlógójì (436) èèyàn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti àádọ́ta (350,000) ló sì ní láti kúrò níbi tí wọ́n ń gbé. Ọ̀kan lára ìmìtìtì tó wáyé náà lágbára gan-an, ṣe ni àwọn ilé wọlẹ̀ ráúráú, ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù owó dọ́là sì làwọn nǹkan tó bà jẹ́.

Ìròyìn tá a gbọ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Jakarta ni pé ìkankan nínú àwọn ará wa ò fara pa, ìkankan ò sì kú, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé àwọn akéde kan bà jẹ́. Bákan náà, ilé tí ìjọ kan ṣoṣo tó wà ní erékùṣù náà ti ń ṣèpàdé bà jẹ́, ogójì (40) akéde ló sì wà nínú ìjọ. Aṣojú méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì rìnrìn àjò lọ síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ yìí kí wọ́n lè mọ ìrànlọ́wọ́ tí àwọn ará ibẹ̀ máa nílò, kí wọ́n sì lè tù wọ́n nínú.

A ò dákẹ́ àdúrà lórí àwọn ará wa lásìkò tí nǹkan nira yìí, torí a mọ̀ pé Jèhófà lè ‘tù wọ́n nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wọn.’—2 Kọ́ríńtì 1:4.