Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 2, 2018
INDONESIA

Ìmìtìtì Ilẹ̀ àti Omíyalé Ṣọṣẹ́ ní Sulawesi, Indonéṣíà

Ìmìtìtì Ilẹ̀ àti Omíyalé Ṣọṣẹ́ ní Sulawesi, Indonéṣíà

Ní Friday, September 28, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára wáyé ní erékùṣù Sulawesi lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Ó ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300) èèyàn tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà àti omíyalé tó tẹ̀ lé e pa, púpọ̀ lára wọn ló ń gbé ní ìlú Palu ní àárín erékùṣù Sulawesi.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ìlú Jakarta ní Indonéṣíà sọ pé kò sí ìkankan tó kú lára ọgọ́rin (80) àwọn ará wa tó wà níbi tí àjálù yìí ti ṣẹlẹ̀. Àwọn díẹ̀ ló fara pa, wọ́n sì ní láti lọ sílé ìwòsàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ba ilé arákùnrin wa kan jẹ́ pátápátá, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa míì sì wà tó ba ilé wọn jẹ́ gan-an. Ilé tí Ìjọ Palu ti ń ṣèpàdé náà tún bà jẹ́.

Ẹ̀ka Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìjọ tó wà nítòsí láti ṣètò bí wọ́n ṣe máa ran àwọn ará lọ́wọ́. Torí pé àwọn ará tó wà níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ ní oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò ìjọ mẹ́ta tí á máa pèsè àwọn nǹkan yìí fáwọn ará tó wà ní Palu. Àwọn alàgbà ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí fáwọn ará, wọ́n ń tù wọ́n nínú, wọ́n sì ń jẹ́ kí wọ́n rí ohun tí wọ́n nílò láti gbé ẹ̀mí wọn ró. Arákùnrin tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ, tó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka pẹ̀lú alábòójútó àyíká ibẹ̀ máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ará tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn kí wọ́n lè tù wọ́n nínú, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí.

À ń gbàdúrà fún àwọn ará wa ní Indonéṣíà, torí a mọ̀ pé Jèhófà á máa jẹ́ “ibi ìsádi àti okun” fún wọn lásìkò wàhálà yìí.—Sáàmù 46:1.