Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÍSÍRẸ́LÌ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì

Àtọdún 1920 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì òde òní, wọ́n sì lómìnira ẹ̀sìn. Lọ́dún 1963 àti 2000, ìjọba forúkọ àwọn àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò láti fi ṣe iṣẹ́ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Lọ́dún 2000 àti 2014, àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀wé síjọba kí wọ́n lè forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀, àmọ́ ìjọba ò tíì fọwọ́ sí i.

Òfin ilẹ̀ Ísírẹ́lì fàyè gba gbogbo ẹ̀sìn tó wà níbẹ̀ láti máa sọ ohun tí wọ́n bá gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. Àmọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Júù tí wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn máa ń ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì máa ń mú kí wọ́n hùwà àìdáa sáwọn Ẹlẹ́rìí lóríṣiríṣi ọ̀nà, kódà, wọ́n á fi orúkọ ẹ̀sìn bojú, wọ́n á wá máa sún àwọn míì hùwà ipá sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì máa yọ wọ́n lẹ́nu.

Láwọn ìgbà míì, àwọn agbawèrèmẹ́sìn yìí máa ń kó sí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan lórí kí wọ́n lè fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí dù wọ́n, títí kan ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti kóra jọ. Láwọn ìgbà kan táwọn aláṣẹ ìlú sì fagi lé àpéjọ tàbí ìpàdé táwọn Ẹlẹ́rìí fẹ́ ṣe láwọn gbọ̀ngàn tí wọ́n yá tó jẹ́ ti ìjọba, àwọn Ẹlẹ́rìí pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Ilé Ẹjọ́ Haifa (lọ́dún 2007) àti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ (lọ́dún 2015) wá sọ pé ṣe ni àwọn aláṣẹ ìlú náà fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣe ẹ̀tanú sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ilé ẹjọ́ yìí dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kóra jọ láìfa wàhálà, kí ẹnikẹ́ni má sì yọ wọ́n lẹ́nu. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò yéé ṣe ẹ̀tanú sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀rọ̀ náà sì ń kọni lóminú.