Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 31, 2019
ÍSÍRẸ́LÌ

A Túbọ̀ Ń Wàásù Níbi Térò Pọ̀ sí Lórilè-Èdè Israel Bí Ẹgḅẹẹgbẹ̀rún Èèyàn Ṣe Ń Ṣèbẹ̀wò Sílùú Tel Aviv

A Túbọ̀ Ń Wàásù Níbi Térò Pọ̀ sí Lórilè-Èdè Israel Bí Ẹgḅẹẹgbẹ̀rún Èèyàn Ṣe Ń Ṣèbẹ̀wò Sílùú Tel Aviv

Ní May 10 sí 19, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Israel sapá gan-an láti túbọ̀ wàásù láwọn ibi térò pọ̀ sí ní ìlú Tel Aviv. Wọ́n fẹ́ ṣe àwọn ọdún ìbílẹ̀ kan ní ìlú náà, èyí sì mú kí àwọn tó ń wá sí ìlú náà ń pọ̀ sí i, torí náà a ṣètò láti wàásù láwọn ibi térò pọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, ní May 14 sí 18, wọ́n ṣe ìdíje orin Eurovision Song Contest ní ìlú Tel Aviv, àwọn tó sì wá síbẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.

Arákùnrin Gennadi Korobov tó bójú tó iṣẹ́ ìwàásù náà sọ pé: “Nígbà tá a gbọ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń bọ̀ níbi ìdíje orin tó máa wáyé ní ìlú Tel Aviv, a gbà pé ó máa fún wa láǹfààní láti túbọ̀ wàásù láwọn ibi térò pọ̀ sí. Ó wúni lórí láti rí àwọn akéde méjìdínláàádọ́sàn-án (168) tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ìjọ méjìlélógún (22) lórílẹ̀-èdè Israel.”

Ojoojúmọ́ làwọn ará yìí pàtẹ àwọn ìwé wa síbi mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti aago mẹ́sàn-án àárọ̀ títí di aago mẹ́sàn-án alẹ́. Torí pé oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè làwọn àlejò tí wá síbẹ̀, àwọn ará kó àwọn ìwé wa ní èdè mẹ́wàá síbi ìpàtẹ náà, ìyẹn: èdè Lárúbáwá, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Gámánì, Hébérù, Italian, Japanese, Russian àti Sípáníìṣì.

Ó dá wa lójú pé iṣẹ́ ìwàásù tá a mú gbòòrò sí i lórílẹ̀-èdè Israel yìí máa sèso rere. Ó sì tún jẹ́ ẹ̀rí tó túbọ̀ ń fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà ń yìn ín “nígbà gbogbo.”—Sáàmù 34:1, 2.