OCTOBER 23, 2019
ÍTÁLÌ
A Ti Ń Kọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun Lórílẹ̀-Èdè Ítálì
Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Ítálì ti ń kó láti ìlú Róòmù lọ sí ìlú Bologna àti Imola. Ìlú Bologna wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lè àádọ́rin (370) kìlómítà sí àríwá ìlú Róòmù, ìlú Imola sì wà ní nǹkan bíi kìlómítà méjìdínláàádọ́ta (48) sí ìlú Bologna. Wọ́n ti ń ṣe àtúnṣe sí ilé alájà mẹ́sàn-án kan tó wà ní ìlú Bologna èyí tí ẹ̀ka máa fi ṣe ọ́fíìsì. Láti ọdún 2018, àwọn òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì tó lé ní ọgọ́ta (60) tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè àtàwọn iṣẹ́ míì tó tan mọ́ ọn ti ń bá iṣẹ́ nìṣó nínú ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àtúnṣe sí ní ìlú Imola.
Ká lè pèsè ibùgbé fún àwọn òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n ń kó lọ sí ìlú Bologna, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé alájà-méje kan sí nǹkan bíi kìlómítà kan àtààbọ̀ (máìlì kan) sí ibi tá a kọ́ ọ́fíìsì sí. Ilé náà ní ibi ìgbọ́kọ̀sí abẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ìpele mẹ́ta. A ṣì tún máa wá àwọn ilé míì sí i ní agbègbè yẹn.
Ọdún 1948 ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àkọ́kọ́ ní ìlú Róòmù tá a sì kó lọ síbẹ̀ láti ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ìlú Milan. Látìgbà yẹn wá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pọ̀ sí i lọ́nà tó pabanbarì ní Ítálì. Ní nǹkan bí ọdún 1945, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà ò ju igba (200) lọ. Lónìí, àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta-lé-nígba (250,000). Orílẹ̀-èdè yìí ló ní iye akéde tó pọ̀ jù nílẹ̀ Yúróòpù. Bí iye àwọn akéde tó wà ní Ítálì ṣe ń pọ̀ sí i ni iye àwọn òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àti ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ń pọ̀ sí i. Ní ọdún 2006, ilé mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ là ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Ítálì. Tá a bá ti pa gbogbo iṣẹ́ pọ̀ sójú kan nílùú Bologna, iye àwọn òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì máa dín kù, á wá ṣẹ́ ku ilé márùn-ún péré.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bá a lọ láti fi ìbùkún rẹ̀ sórí iṣẹ́ ìkọ́lé náà kí àwọn ọ́fíìsì tuntun náà sì ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe ní Ítálì, pápá tó ‘funfun tó sì ti tó kórè.’—Jòhánù 4:35.