Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ààfin Ìdájọ́ ní Ìlú Róòmù, níbi tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tó Ń Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ẹjọ́ Wà Lórílẹ̀-Èdè Ítálì

OCTOBER 1, 2019
ÍTÁLÌ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Ítálì Gbà Nínú Ẹjọ́ Àbójútó Ọmọ Pé Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba ni Òbí Méjèèjì Ní Láti Kọ́ Ọmọ Lẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Ítálì Gbà Nínú Ẹjọ́ Àbójútó Ọmọ Pé Ẹ̀tọ́ Ọgbọọgba ni Òbí Méjèèjì Ní Láti Kọ́ Ọmọ Lẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tó Ń Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ẹjọ́ nílùú Róòmù (ìyẹn Supreme Court of Cassation) ṣe ìdájọ́ pàtàkì kan ní August 30, 2019. Ìdájọ́ náà dá lórí ọ̀rọ̀ ẹni tó máa mú ọmọ sọ́dọ̀ àti ẹ̀tọ́ tí àwọn òbí ní níbi tó ti jẹ́ pé òbí méjèèjì kò sí pa pọ̀ mọ́. Ilé ẹjọ́ gíga jù lọ tó wà ní orílẹ̀-èdè Ítálì pinnu pé obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ní ẹ̀tọ́ láti kọ́ ọmọ rẹ̀ tí kò tíì tójúúbọ́ ní ohun tó gbà gbọ́.

Bàbá ọmọ náà tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tí kò sì gbé pẹ̀lú ìyá ọmọ náà mọ́ yarí pé ohun tí bàbá gbà gbọ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n fi kọ́ ọmọ. Ilé ẹjọ́ kékeré méjì fara mọ́ èrò bàbá náà, wọ́n sì sọ pé bí wọ́n bá fi ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn míì kọ́ ọmọ náà, ó lè “dà á lọ́kàn rú.” Ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí ò ní jẹ́ kí ìyá lè fi ohun tó gbà gbọ́ kọ́ ọmọ rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fagi lé ìpinnu àwọn ilé ẹjọ́ kékeré náà, ó sì fi òté lé e pé “ẹ̀tọ́ ọgbọọgba ni òbí méjèèjì” ní lórí ọmọ wọn tí kò tíì tójúúbọ́. Ilé ẹjọ́ náà tún mú kó ṣe kedere pé “òfin ò gbé ẹ̀sìn kan ga ju ìkejì lọ” ó sì dẹ́bi fún ohun tó pè ní ìwà “ẹ̀tanú” tí àwọn ilé ẹjọ́ kékeré náà hù sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìpinnu yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí ohùn òbí méjèèjì ò bá ṣọ̀kan lórí ẹni tó yẹ kó kọ́ ọmọ wọn ní ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n gbà gbọ́, adájọ́ ò ní ẹ̀tọ́ láti pinnu fún wọn pé ẹ̀sìn kan ló sàn jù ìkejì lọ.

A nírètí pé ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ ṣe yìí á jẹ́ àwòkọ́ṣe lọ́jọ́ iwájú tí àwọn ẹjọ́ míì nípa ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ bá wáyé lórílẹ̀-èdè Ítálì. Ó dájú pé ìyẹn á ṣàǹfààní gan-an fún àwọn òbí tó ń sapá láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.”—Éfésù 6:4.