NOVEMBER 12, 2020
ÍTÁLÌ
Ilé Ẹjọ́ Kan Lórílẹ̀-Èdè Ítálì Fara Mọ́ Ọn Pé Àwọn Òbí Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Pinnu Irú Ìtọ́jú Ìṣègùn Táwọn Ọmọ Wọn Máa Gbà
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní Milan lórílẹ̀-èdè Ítálì fara mọ́ ìpinnu tí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣe lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ kí wọ́n tọ́jú ọmọ wọn nílé ìwòsàn. Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ káwọn ilé ẹjọ́ tó kù rí i pé wọn ò lè tìtorí pé òbí kan ò gbà kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ òun lára, kí wọ́n wá dórí ìpinnu pé òbí náà ò lè tọ́jú ọmọ ẹ̀ dáadáa. Ilé ẹjọ́ tún sọ pé tí ìgbàgbọ́ òbí kan ò bá fàyè gbà á láti fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ ẹ̀ lára, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu pé ọmọ òun ò ní gbẹ̀jẹ̀.
Ní September 2019, tọkọtaya kan gbé ọmọbìnrin wọn olóṣù mẹ́wàá lọ sílé ìwòsàn torí pé ó ṣubú, ó sì forí gbá. Àwọn dókítà rí i pé àfi káwọn ṣiṣẹ́ abẹ fún un kára ẹ̀ tó lè yá. Wọ́n sì ṣe iṣẹ́ abẹ yìí láṣeyọrí láìfa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ náà lára.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ọmọ yìí ti ń yá, kò sì sí ìṣòro kankan, síbẹ̀ dókítà kan ní káwọn òbí ọmọ náà gba òun láyè láti fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ náà lára kára ẹ̀ tún lè yá sí i. Làwọn òbí yẹn bá sọ pé kí wọ́n lo ìtọ́jú tí wọ́n máa ń lò tí wọn ò bá fẹ́ fá ẹ̀jẹ̀ séèyàn lára.
Dípò kí dókítà yìí ṣe ohun táwọn òbí ọmọ náà fẹ́, ṣe ló lọ pe àwọn ọlọ́pàá àtàwọn agbẹjọ́rò ìjọba. Làwọn agbẹjọ́rò yìí bá gbé àwọn òbí ọmọ náà lọ sílé ẹjọ́ tí wọ́n ti ń dá sọ́rọ̀ àwọn lọ́kọláya. Ilé ẹjọ́ yìí gba ẹ̀tọ́ táwọn òbí náà ní lórí irú ìtọ́jú ìṣègùn tọ́mọ wọn máa gbà, wọ́n sì sọ pé ọ̀gá ilé ìwòsàn ni kó pinnu bí wọ́n ṣe máa tọ́jú ọmọ náà. Àmọ́, àwọn dókítà ò fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ náà lára, torí wọn ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
Ká tó wí, ká tó fọ̀, ìròyìn yìí ti tàn kálẹ̀, ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ló sì gbé ọ̀rọ̀ yìí sáfẹ́fẹ́. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn oníròyìn tó wà lórílẹ̀-èdè Ítálì ló bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi ohun tí ò jóòótọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ní ọpẹ́lọpẹ́ ilé ẹjọ́ tó ní àfi dandan kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ náà lára, ọmọ yẹn ì bá ti kú.
Ní September 10, 2020, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn fagi lé ìdájọ́ tílé ẹjọ́ tó ń dá sọ́rọ̀ àwọn lọ́kọláya ṣe. Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tún sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe iṣẹ́ ilé ẹjọ́ tó ń dá sọ́rọ̀ àwọn lọ́kọláya, torí náà wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti dá sí i.
Nínú ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní Milan ṣe, wọ́n sọ pé: “Ohun táwọn òbí yẹn gbà gbọ́ ló fà á tí wọn ò fi gbà kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ wọn lára. Torí náà, a ò lè tìtorí ìyẹn sọ pé wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́jú ọmọ wọn, ká wá gba ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti tọ́jú ọmọ náà.” Láàárín ọdún tó kọjá, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Ítálì ló fara mọ́ ọn pé àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fáwọn dókítà pé kí wọ́n lo ìtọ́jú ìṣègùn tí ò ní gba pé kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sọ́mọ wọn lára.
Ó ṣe pàtàkì káwọn ilé ẹjọ́ àtàwọn oníṣègùn mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo oògùn, wọn ò sì retí pé ara wọn máa yá lọ́nà ìyanu. Kódà, wọ́n dìídì máa ń wá ìtọ́jú lọ sáwọn ilé ìwòsàn tó mọṣẹ́, tó nírìírí, tó sì láwọn irinṣẹ́ ìgbàlódé, kí wọ́n lè rí ìtọ́jú tó dáa gbà láìṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ ò ju pé káwọn dókítà tọ́jú àwọn láìfa ẹ̀jẹ̀ sáwọn lára. Ọ̀pọ̀ àwọn dókítà tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ láwọn ilé ìwòsàn tó lóókọ kárí ayé ló ti gbà láti tọ́jú àwọn aláìsàn láìfa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára, kódà àwọn ìtọ́jú tí wọ́n ń ṣe báyìí ti wá dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Inú wa dùn pé ìdájọ́ tílé ẹjọ́ ṣe yìí á jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará wa láti dúró lórí ìpinnu wọn pé àwọn ò ní gbà kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sára ọmọ àwọn.—Ìṣe 15:29.