Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwòrán ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Gaeta tẹ́lẹ̀, lórílẹ̀-èdè Ítálì, níbi tí wọ́n fi àwọn arákùnrin wa kan sí torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun

JULY 9, 2020
ÍTÁLÌ

Ohun Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Mú Kí Ìjọba Ilẹ̀ Ítálì Fọwọ́ Sí I Pé Èèyàn Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Sọ Pé Òun Ò Ṣiṣẹ́ Ológun

Ohun Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Mú Kí Ìjọba Ilẹ̀ Ítálì Fọwọ́ Sí I Pé Èèyàn Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Sọ Pé Òun Ò Ṣiṣẹ́ Ológun

Orílẹ̀-èdè Ítálì ti wà lára ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó gbà pé àwọn aráàlú lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́ bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀ kọ́ nìyẹn. Ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara da ìyà, wọn ò sì bọ́hùn nígbà tí wọ́n tì wọ́n mọ́lé torí pé wọn ò fẹ́ wọṣẹ́ ológun.

Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, orílẹ̀-èdè Ítálì ṣì ń fipá mú àwọn ọkùnrin wọṣẹ́ ológun. Ní 1946, lẹ́yìn tí ogun náà parí, iye Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Ítálì ò ju ọgọ́fà (120) lọ. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni iye àwọn tó ń yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọ̀dọ́ tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti wọṣẹ́ ológun ń pọ̀ sí i. Ìdí tí wọn ò fi wọṣẹ́ ológun ni pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ ogun, wọn ò gbọ́dọ̀ fa wàhálà láàárín ìlú, wọ́n sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn míì.

Nínú ìwádìí kan tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Ítálì ṣe, wọ́n rí i pé ó kéré tán, àwọn arákùnrin wa tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ọgọ́sàn-án (14,180) tí ìjọba rán lọ sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun ló ṣì wà láàyè. Àròpọ̀ iye ọdún tí wọ́n lò lẹ́wọ̀n láàárín ọdún 1965 sí 1998 jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gbọ̀n (9,732).

Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Sergio Albesano ní ìlú Turin lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé “àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló pọ̀ jù lára àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.” Ó tún sọ pé, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó gbà láti lọ sẹ́wọ̀n dípò kí wọ́n wọṣẹ́ ológun, “àwọn ló jẹ́ kí ìṣòro náà bọ́ sójú táyé.”

Nígbà tí Giulio Andreotti ṣì jẹ́ mínísítà fún ọ̀rọ̀ ààbò lórílẹ̀-èdè Ítálì lọ́dún 1959 sí 1966, ó dìídì lọ bá àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n kó lè mọ ìdí tí wọ́n fi kọ̀ jálẹ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Ó sọ pé: “Bí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣe dá wọn lójú, tí wọn ò sì dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú jọ mí lójú gan-an. Kì í ṣe pé ó kàn wù wọ́n láti ṣẹ̀wọ̀n, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló jẹ́ kí wọ́n fara da ìyà àti ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́wọ̀n.”

Ọdún 1972 làwọn ará ìlú kọ́kọ́ lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti kọ iṣẹ́ ológun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó bófin mu pé àwọn èèyàn lè máa ṣiṣẹ́ sìnlú, àwọn ológun ló ṣì ń darí ètò náà, èyí ò sì bá àwọn ará wa lára mu.

Àmọ́ ní July 8, 1998, ìjọba orílẹ̀-èdè Ítálì ṣe òfin tuntun kan pé àwọn ológun ò láṣẹ mọ́ láti máa darí iṣẹ́ táwọn èèyàn ń ṣe sìnlú, òfin tuntun yìí sì bá ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ mu. Ní August 2004, orílẹ̀-èdè Ítálì ṣe òfin tuntun pé bẹ̀rẹ̀ láti January 2005, wọn ò ní fi dandan mú àwọn ọkùnrin wọṣẹ́ ológun mọ́.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn ni agbẹjọ́rò kan tó ń jẹ́ Sergio Lariccia láti Sapienza University nílùú Róòmù. Ó sọ pé: “Nígbà tí àwọn ológun tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn sọ pé ‘ojo ni ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, pé onítọ̀hún ń tàbùkù sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ àti pé iṣẹ́ ogun ò ní kéèyàn má nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀,’ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró digbí, wọn ò sì bọ́hùn láìka ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n sí. Ìyẹn ló jẹ́ kí ìjọba orílẹ̀-èdè Ítálì pèrò dà, kí wọ́n sì tún òfin tó ti wà tẹ́lẹ̀ ṣe.”

Ohun táwọn ará wa ṣe tún jẹ́ káwọn nǹkan míì ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn wọ́dà ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n rí ìwà àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n. Ọ̀kan lára wọn ni Giuseppe Serra, ó ní: “Àpẹẹrẹ rere àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ló mú . . . kí n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ọdún 1972 ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.)

Inú wa dùn gan-an pé àwọn arákùnrin wa lo ìgboyà, wọ́n sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ará àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn lórílẹ̀-èdè Ítálì, títí kan àwọn ará kárí ayé, bí wọ́n ṣe pinnu pé àwọn ò “ní kọ́ṣẹ́ ogun.”​—Àìsáyà 2:4.