SEPTEMBER 26, 2019
ÍTÁLÌ
Lórílẹ̀-Èdè Ítálì, Wọ́n Ṣí Aṣọ Lójú Àmì Tó Ń Ránni Létí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Ẹgbẹ́ Òṣèlú Násì àti Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ Ṣe Inúnibíni Sí
Ní May 10, 2019, àwọn aláṣẹ ìjọba, àwọn òpìtàn, àwọn akọ̀ròyìn, àti ọ̀pọ̀ àlejò míì wá síbi ètò kan tí wọ́n ti ṣí aṣọ lójú àmì tí wọ́n ṣe ní ìrántí ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ẹgbẹ́ òṣèlú Násì àti Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ṣe inúnibíni sí. Ètò ìrántí náà wáyé ní abúlé Risiera di San Sabba ní ìlú Trieste, tó wà ní àríwá ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Ítálì. Abúlé yìí ni wọ́n ti ń fi ẹ̀rọ fẹ́ ìrẹsì tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó sọ ọ́ di àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan ṣoṣo lórílẹ̀-èdè Ítálì tó ní ibi tí wọ́n ti ń dáná sun òkú. Àwọn ilé iṣẹ́ oníròyìn ti àdúgbò àti ti ìjọba náà wá síbi tí wọ́n ti ṣí aṣọ lójú àmì ìrántí náà, tó fi mọ́ Canale 5, tó jẹ́ ìkànnì tẹlifíṣọ̀n táwọn èèyàn ń wò jù lọ lórílẹ̀-èdè náà.
Àsọyé kan tó dá lórí ìdúróṣinṣin ni Christian Di Blasio, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni orílẹ̀-èdè Ítálì fi bẹ̀rẹ̀ ètò ìrántí náà. Ó sọ pé: “Lára àwọn tí ìjọba Násì ṣe inúnibíni sí, àwọn ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo ló jẹ́ pé kìkì nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ni ìjọba Násì ṣe ṣe inúnibíni sí wọ́n. Àwọn nìkan ni sì àwùjọ tó ní àǹfààní láti ṣe nǹkan kan tí ikú á fi yẹ̀ lórí wọn. Kí wọ́n wulẹ̀ sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn ni, kí wọ́n sì sọ pé ti ìjọba làwọn á ṣe. Síbẹ̀, wọ́n ní ìgboyà tó mú kí wọ́n dúró lórí ìwà tó yẹ ká bá lọ́wọ́ Kristẹni, ìyẹn ni pé wọ́n ní jẹ́ adúróṣinsin sí Ọlọ́run, wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.” Lẹ́yìn yẹn ni Arákùnrin Di Blasio fi fídíò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Arábìnrin Emma Bauer han àwọn tó wà níkàlẹ̀. Nínú fídíò náà, Arábìnrin Emma Bauer ròyìn bi òun àti ìdílé òun ṣe fojú winá inúnibíni nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ó ṣàlàyé pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ò ní yẹsẹ̀ lórí ohun tó tọ́, kódà tó bá máa la ikú lọ. Ní ìparí ètò ìrántí náà, olórí ìlú Trieste, Roberto Dipiazza, bá àwọn tó wá síbẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó ní: “Àmì ìrántí yìí dùn mọ́ mi nínú gan-an. A gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe kí irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ mọ́ láé.” Ẹ̀yìn yẹn ni wọ́n wá ṣí aṣọ lójú àmì ìrántí náà.
Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé àtàwọn ìlúmọ̀ọ́ká sọ̀rọ̀ lórí bí ètò ìrántí náà ti ṣe pàtàkì tó. Bí àpẹẹrẹ, Giorgio Bouchard, ààrẹ àná fún Àgbájọ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere Lórílẹ̀-Èdè Ítálì sọ pé: “Yàtọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sí àwùjọ ẹ̀sìn náà táwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ tíì fẹ̀mí ara wọn lélẹ̀ tó báyìí rí nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. . . . Àmọ́, ṣe ni ìrírí tó le koko táwọn Ẹlẹ́rìí ní yìí túbọ̀ mú kí wọ́n lágbára. Wọ́n sì wá fìdí ẹ̀rí múlẹ̀ fáwọn èèyàn, àti fún Ọlọ́run pàápàá, pé àwọn ni ẹ̀sìn Kristẹni kan ṣoṣo tó ta ko èròǹgbà tí Ìjọba Násì gbé lárugẹ.” (Fún àlàyé síwájú sí i, wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.)
A nírètí pé àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà (120,000 ) lá máa ṣèbẹ̀wò síbi àmì ìrántí pàtàkì tó wà ní abúlé Risiera di San Sabba yìí lọ́dọọdún. Ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá wá síbẹ̀ á ní àǹfààní láti wo àmì yìí ní ìrántí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó dúró lórí ìgbàgbọ́ wọn tí wọn ò sì lọ́wọ́ sí òṣèlú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú Násì àti ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ ṣe inúnibíni sí wọn.—Ìfihàn 2:10.